Kẹhinde dana sun ale ọkọ ẹ l’Ọta

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Obinrin ọlọmọ mẹta kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Kẹhinde Abdul Wasiu, ti bọ sọwọ ọlọpaa l’Ọta bayii, bẹẹ si lọkọ rẹ naa, Ismail Wasiu, ti wa lakolo ọlọpaa pẹlu, nitori iku ale Wasiu to n jẹ Tosin Olugbade.

Alaye ti DSP Abimbọla Oyeyẹmi ṣe ni pe ọkọ Tosin lo mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa Ọta, lọjọ  kejilelogun, oṣu kọkanla, pe lasiko kan ninu oṣu kẹjọ, ọdun yii, oun fura pe iyawo oun n yan Ismail Wasiu lale, oun si gbe e ko o loju pe o n rin irinkurin.

O ni si iyalẹnu oun, niṣe ni Tosin, ẹni ọdun mẹtalelogun, kẹru jade nile oun, o si kuku ko lọ sile Wasiu toun sọ pe o n yan lale.

Ọkunrin yii tẹsiwaju pe lọjọ kẹrinla, oṣu kọkanla, to kọja yii, oun gbọ pe iyawo Wasiu ati iyawo oun ja, iyawo Wasiu to n jẹ Kẹhinde si da bẹntiroolu siyawo oun lara, lo ba ṣana si i.

Awọn ẹbi Tosin lo tun gbe e lọ sọsibitu, ṣugbọn nibi ti wọn ti n tọju ẹ lo ku si gẹgẹ bi ọkọ obinrin to doloogbe naa ṣe ṣalaye fawọn ọlọpaa.

Awọn ọlọpaa lọ sile Wasiu, wọn mu un, nitori iyawo rẹ to dana sun Tosin ti sa lọ ni tiẹ lẹyin iṣẹlẹ naa. Wọn lọkọ rẹ lo ni ko tete sa lọ kọwọ ofin too to o. Eyi ni wọn ṣe mu Wasiu to ko iyawo to bimọ mẹta fun un ati ale pọ sinu ile kan ṣoṣo.

Ninu iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ awọn ọlọpaa ni wọn ti pada ri Kẹhinde to dana sun obinrin naa mu, ilu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn ti mu un.

Kẹhinde to dana sun Tosin ṣalaye pe loootọ loun dana sun obinrin yii, o ni ṣugbọn oun ko mọ ohun to ti oun siru ẹ toun fi ṣe e.

Ko too jẹwọ yii, iwadii awọn ọlọpaa fi han pe niṣe ni Wasiu ati Kẹhinde purọ fawọn ẹbi Tosin pe gaasi to fi n dana lo bu gbamu, to si jo o pa, ṣugbọn nigba ti aṣiri irọ ti wọn pa naa tu ni ọkọ sọ funyawo ẹ pe ko tete maa sa lọ kọwọ ofin ma baa to o.

 Wọn yoo gbe tọkọ-taya yii lọ si kootu lẹyin iwadii awọn ọlọpaa, gẹgẹ bi CP Lanre Bankọle ṣe wi.

Leave a Reply