Jide Alabi
O jọ pe ọna kan tawọn eeyan tun gba fi n fẹhonu han bayii lai jo ile tabi ba dukia kankan jẹ ni bi wọn ti ṣe n lọ si gbogbo ibi ti ijọba ko ounjẹ to yẹ ki wọn fun wọn lasiko isemọle ajakalẹ arun koronafairọọsi pamọ si, ti wọn si n ko o lọ sile wọn.
Bi wọn ti ṣe n ja ibi iko-ounjẹ pamọ si l’Ekoo, bẹẹ lo ṣẹlẹ l’Ẹdẹ, ni bayii, ilu Ilọrin ni Kwara lawọn eeyan tun ti ya sita bayii, ti kaluku si n sare lẹlẹlẹ lọ sibi ti ijọba ko ounjẹ to yẹ ko pin fun wọn pamọ si.
Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe, papakọ ofurufu to wa ni Ilọrin ni kaluku wọn gba lọ, nibi ti wọn ti lọọ n ko irẹsi, ṣuga, iyọ atawọn ohun jijẹ ati mimu mi-in.
Wọn ni, gbogbo akitiyan awọn ẹṣọ agbofinro lati ṣi wọn lọwọ ni ko so eso rere, ti kaluku si n fi idunnu ru apo ẹwa ati irẹsi lo sile wọn
O jọ pe ọna kan tawọn eeyan tun gba fi n fẹhonu han bayii laijole tabi ba ohunkohun jẹ ni bi wọn ti ṣe n lọ si gbogbo ibi ti ijọba ko ounjẹ to yẹ ki wọn fun wọn lasiko isemọle ajakalẹ arun koronafairọọsi si, ti wọn si n ko o lọ sile wọn.