Awọn eeyan fẹhonu han ta ko eto iforukọsilẹ ẹgbẹ APC ni Kwara

Stephen Ajagbe, Ilorin

Wahala to n ba ẹgbẹ oṣelu to n ṣejọba nipinlẹ Kwara, APC, finra gbọna mi-in yọ laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, nigba tawọn olufẹhonu han kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ naa ya bo ile ijọba, niluu Ilọrin, lati ta ko eto iforukọsilẹ awọn ọmọ ẹgbẹ to n lọ lọwọ.

Awọn olufẹhonu han naa pẹlu akọle oriṣiiriṣii ti wọn gbe lọwọ fẹsun kan Gomina Abdulrahman Abdulrazaq pe o ti ja eto naa gba fun anfaani ara rẹ.

Wọn ni gomina ti fi ọgbọn foju igbimọ to n mojuto eto iforukọsilẹ naa mọra ki wọn le ṣe ohun to nifẹẹ si.

Ohun ti wọn n sọ ni pe ẹgbọn Gomina Abdulrahman, iyẹn Senatọ Khairat Gwadabe-Abdulrazak, lo fa alaga igbimọ to n mojuto eto iforukọsilẹ naa kalẹ, fun idi eyi, awọn ko nigbagbọ ninu ẹ rara.

Ṣe lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lẹgbẹ APC fa gbogbo awọn ohun eelo fun eto iforukọsilẹ naa le Alaga APC tuntun ni Kwara, Abdullahi Samari, lọwọ ta ko ifẹ awọn alatilẹyin alaga tẹlẹ ti wọn yọ loye, Bashiru Ọmọlaja Bọlarinwa (BOB).

Leave a Reply