Awọn Fulani darandaran lọọ ka awọn agbẹ mọ inu oko wọn l’Akurẹ, wọn si ṣa wọn bii ẹran

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọrọ awọn Fulani darandaran to n ṣoro bii agbọn nipinlẹ Ondo tun ba ọna mi-in yọ l’ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, pẹlu bi wọn ṣe lọọ ka awọn agbẹ kan mọ inu oko wọn nitosi Akurẹ, ti wọn si kun ẹni kan bii ẹni kun ẹran.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o waye ninu oko ẹgẹ nla kan ti wọn n pe ni Owobamigbe, eyi to wa loju ọna abule Ilẹyọ Isagba, niluu Akurẹ.

Ọkunrin kan ti wọn lo jẹ ọmọ ọkan ninu awọn agbẹ to n dako ẹgẹ lagbegbe naa lo deedee ṣabẹwo sinu oko lọsan-an ọjọ naa to si ba awọn darandaran ọhun ti wọn n fa ẹgẹ ti wọn fowo iyebiye gbin tu lori ebe, ti wọn si n fun awọn maaluu tí wọn n da jẹ.

Ibi to ti n gbiyanju ati ṣi wọn lọwọ iṣẹ ibi ti wọn n ṣe lawọn Fulani ọhun ti kọju ija si i, ti wọn si n ṣa a ladaa ni gbogbo ara.

Gbogbo awọn ara abule to sa jade lati waa gba ọmọkunrin naa silẹ lọwọ wọn lawọn darandaran naa tun kọ lu, ti wọn si ṣe wọn léṣe ki wọn too raaye sa mọ wọn lọwọ.

Ọkan ninu awọn eeyan abule ọhun, Abiọdun Michael to b’ALAROYE sọrọ ni ọpọ awọn olugbe abule ọhun ni wọn ti ko ẹru wọn, ti wọn si ti n sa kuro nitori ibẹru awọn Fulani ọhun.

O ni ko sẹni to ṣetan ati sun ile rẹ labule naa titi tijọba yoo fi wa nnkan ṣe lori iṣẹlẹ naa nitori pe o ti di aṣa awọn Fulani ọhun lati waa maa kọ lu awọn loru nigbakuugba ti ede aiyede ba ti waye laarin awọn.

Leave a Reply