Awọn Fulani tun ya wọ Ikọtun, ni Kwara, lawọn araalu ba le wọn pada 

Stephen Ajagbe, Ilorin

Ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu, NSCDC, ẹka tipinlẹ Kwara, ti ṣawari ibudo kan tawọn Fulani darandaran ti wọn wọ ilu wa laarin oru tẹdo si niluu Ikọtun, nipinlẹ Kwara.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanla, oṣu karun-un, lawọn araalu ṣadeede ri awọn Fulani ọhun pẹlu ọpọlọpọ ẹru ti wọn ru wa, nibi ti wọn gunlẹ si.

Alukoro NSCDC, Babawale Zaid Afọlabi, sọ pe ilu Ikọtun lo ta ajọ naa lolobo nipa awọn ajeji ti wọn ṣadeede ri ti wọn n ya wọnu ilu wọn wa naa.

O ni lai fi akoko ṣofo, Kabiyesi Olukọtun pe awọn ọdẹ, fijilante ilu atawọn ẹṣọ alaabo; ọlọpaa, NSCDC, DSS, si ipade pajawiri lati wa ọna bi wọn ṣe maa le awọn Fulani naa pada sibi ti wọn ti wa.

Afọlabi ni nigba tawọn beere ohun ti wọn n wa, idahun wọn ni pe ilu Kaiama, nipinlẹ Kwara, lawọn ti wa, ibatan awọn kan to n jẹ Tambaya lawọn waa ba lati jọ maa gbe papọ ati ̀lati maa ṣiṣẹ oko.

O ni lẹyin ipade naa ilu ni awọn ko fẹ wọn lọdọ awọn, ni wọn ba paṣẹ pe ki wọn pada sibi ti wọn ti n bọ ki ilẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, too ṣu.

Leave a Reply