Taofeek Surdiq
Ado-Ekiti
Kayeefi nla lo jẹ fun gbogbo awọn eeyan to wa adugbo Moferere, niluu Ado-Ekiti, pẹlu bi wọn ṣe ṣadeede ba ọmọ tuntun jojolo kan ninu ile akọku kan ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Niṣe ni wọn ba ikoko ọhun nibi to ti n ju apa ati ẹsẹ, lori ọra dudu kan ti wọn tẹ ẹ si pẹlu iwọ ati ibi ọmọ naa ninu agbara ẹjẹ.
Awọn araadugbo naa ṣalaye fun ALAROYE pe ni deede aago mẹjọ aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, yii ni ọkunrin kan to jẹ araadugbo naa n kọja lọ, to si ri ọmọde jojolo naa nibi ti wọn tẹ ẹ si, to si n kigbe soke lẹẹkọọkan. Ọkunrin yii ni igbe ọmọ yii lo mu ki oun ya wo inu ile naa, boun si ṣe ri ọmọ yii loun kigbe pe awọn araadugbo.
Ariwo ọkunrin yii lawọn eeyan naa gbọ ti gbogbo wọn fi sare jade, ti wọn si n rọ lọ sinu ile naa ti apa kan rẹ ti wo lulẹ.
Epe buruku lawọn to ri ọmọ yii n ṣẹ le ọdaju abiyamọ to gbe e sibẹ lori. Awọn araadugbo yii lo gbe ọmọ ọhun, ti wọn si lọọ fi ohun to ṣẹlẹ to awọn ọlọpaa leti.
Obinrin kan to ni ile iwosan aladaani kan laduugbo naa lo gbe ọmọ yii lọ si ọsibitu rẹ, ti wọn si tọju rẹ. Ọsibitu yii ni awọn ọlọpaa ti ba a.
Awọn agbofinro lo pada gbe ọmọ jojolo yii lọ si ile awọn alailobii kan to wa niluu Iyin-Ekiti, nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, ọga ọlọpaa kan to wa ni Ọlọgẹdẹ, ni agbegbe ọhun, juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii ohun to buru gbaa, o fi kun un pe ni kete ti wọn fi iṣẹlẹ naa to oun leti loun ti ran awọn ikọ agbofinro kan lọ si agbegbe naa, ti wọn si ti gbe ọmọ tuntun jojolo naa lọ si ile awọn ọmọ alailobii lẹyin to ti gba itọju to peye tan nileewosan aladaani kan to wa ni agbegbe naa.
Ninu ọrọ tiẹ, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe ileeṣẹ awọn ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa, ati pe awọn ti tun gbe igbimọ kan dide lati wa obi ọmọde jojolo naa kan.