Awọn Fulani ya wọ Babanla, ni Kwara, lawọn araalu ba le wọn danu

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọ Aiku, Sannde, ọṣẹ yii, lawọn Fulani darandaran ya wọ ilu Babanla, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, ,ipinlẹ Kwara, lati tẹdo sibẹ, ṣugbọn niṣe lawọn araalu le wọn danu, wọn ni ibagbepọ wọn ko le rọgbọ.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ẹsọ alaabo (NSCDC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, Babawale Zaid Afọlabi, fi lede ni ilu Ilọrin lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti ṣalaye pe, awọn afurasi Fulani darandaran ya wọ ilu Babanla, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, ti wọn si fẹẹ fi agbegbe naa ṣe ibugbe, bẹẹ ni ko si ẹni to mọ ibi ti wọn ti wa.

O tẹsiwaju pe ni kete ti awọn Fulani ọhun gunlẹ si ilu ọhun ni wọn ti ta ikọ awọn lolobo, nigba tawọn si de agbegbe naa, awọn yẹ ọkọ ti wọn gbe wa wo finni finni, awọn ko si ba ohun ija oloro kankan ninu ọkọ naa.

Afọlabi ni ẹsọ alaabo awọn ti waa pawọ-pọ pẹlu awọn araalu lati le wọn kuro ni agbegbe naa latari pe awọn araalu ni ibagbepọ awọn ko le rọgbọ.

Leave a Reply