Awọn gomina ilẹ Yoruba ṣepade bonkẹlẹ niluu Eko

Faith Adebola

Irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lawọn gomina lati ilẹ Yoruba ṣepade bonkẹlẹ nile ijọba, nipinlẹ Eko, nibi ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ti gba wọn lalejo.

Ni nnkan bii aago mẹrin aabọ irọlẹ ni wọn bẹrẹ ipade naa, eyi ti wọn ṣe ni bonkẹlẹ, ti wọn ko si sọ ohun ti wọn tori ẹ pepade ọhun tabi ohun ti wọn fẹnu ko le lori fun oniroyin kankan.

Gbogbo awọn gomina maraarun lati ipinlẹ to wa ni ilẹ Yoruba, Ọyọ, Ọṣun, Ogun, Ondo, Ekiti ati Eko lo wa nibẹ. Bo tilẹ jẹ pe Ọgbẹni Rauf Ọlaniyan to jẹ igbakeji gomina Ọyọ lo waa ṣoju ọga rẹ.

Lẹyin ipade naa ni Gomina ipinlẹ Ondo to tun jẹ adari awọn gomina ilẹ Yoruba sọ fun awọn oniroyin pe diẹ lara ohun ti ipade naa da le lori ni ọrọ eto aabo. Bẹẹ lo sọ pe awọn ko ṣetan ati sọ ohun ti awọn ṣepade le lori fun awọn oniroyin.

Lẹyin ipade ti wọn ṣe fun bii wakati kan aabọ ọhun ni wọn kọri si ile-ijọba ni Marina.

Leave a Reply