Awọn Ibo binu tan, wọn ti gbogbo ṣọọbu wọn pa n’llọrin, wọn lawọn o taja mọ

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni awọn ontaja ẹya Igbo, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, binu tan, ti wọn si ni awọn ko ni i taja fun ẹnikankan mọ niluu naa, ni wọn ba ti gbogbo ṣọọbu wọn pa fẹsun pe ijọba Kwara ti fẹẹ fi owo-ori ba tawọn jẹ.

Gbogbo ile itaja wọn jake-jado ilu Ilọrin, ni wọn ti gbe kọkọrọ sẹnu ilẹkun wọn, ti kara-kata  kankan ko si waye mọ lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta yii, ti wọn si ni awọn ko ni i silẹkun naa titi ti ijọba Kwara yoo fi dahun si ibeere awọn.

ALAROYE ri awọn ontaja ẹya Igbo naa nibi ti wọn kora jọ si lagbegbe Taiwo, niluu Ilọrin, labẹ ẹgbẹ ontaja ẹya Igbo (Association of Igbo Traders) lati jiroro ati lati fẹnu ko lori ohun to kan ni ṣiṣe.

Ọkan lara ọmọ ẹgbẹ naa to bẹbẹ ka forukọ bo oun laṣiiri sọ pe ajọ to n pa owo wọle fun ijọba ipinlẹ Kwara (Kwara State Internal Revenue Service), lo ti sọọbu eeyan meji lara awọn pa lori ọrọ owo-ori sisan.

O ni igbesẹ naa lo fa a ti awọn yooku fi dara pọ mọ wọn lati gbeja wọn, nitori wọn ni ohun to ba de ba oju, o de ba imu ni.

O ni ti awọn ko ba dara pọ mọ awọn meji ọhun, awọn mọ wi pe awọn yooku naa ko le mori bọ ninu igbesẹ naa, nitori ijọba yoo pada ti ile itaja tawọn naa pa.

O salaye pe kọda, ko jẹ ọdun kan tabi ju bẹẹ lọ ni ijọba lo lati si awọn ṣọọbu naa, awọn naa ko ni i taja fun ẹnikẹni fun iye ọdun naa.

Awọn ṣọọbu meji tijọba ti pa ni: ileetaja aṣaraloge Chupet, ati ileetaja ohun mimu ẹlẹridodo Top Bizz.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, gbọnmi-si-i-omi-o-to-o lo waye laarin awọn ẹya Igbo to ni ṣọọbu naa ati ajọ to n pa owo wọle funjọba ipinlẹ Kwara, lori owo-ori.

Wọn ni owo-ori tijọba ni ki awọn eeyan naa maa san jẹ eyi to buaya, ti o si le pa ileeṣẹ awọn run.

Wọn ni lati ibẹrẹ, latọwọ ẹgbẹ ẹya Igbo lawọn maa n gba sanwoori, tawọn si n san an deede, ṣugbọn lojiji nijọba ni ki onikaluku maa san owo rẹ lọtọ, pe awọn ko gba a latọwọ ẹgbẹ wọn mọ.

O tẹsiwaju pe ohun to jọ awọn loju ni pe obitibiti miliọnu Naira ni wọn bu fun ẹni kọọkan awọn fun owo-ori ọdun kan.

L’ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni alaga ajọ to n pawo wọle fun ijọba Kwara, Shade Omoniyi, ti fi lede pe ajọ naa ko gba owo-ori pẹlu ẹlẹyamẹya gẹgẹ bi wọn ṣe n gbe e kiri, o ni awọn ṣiṣẹ awọn pẹlu liana, ati ni ibamu pẹlu ofin ni. O fi kun un pe awọn ti ṣetan lati maa ṣiṣẹ awọn lai fa wahala pẹlu ẹnikẹni.

Leave a Reply