Lẹyin ọjọ mẹsan-an lakata awọn ajinigbe, oyinbo Chinese ti wọn ji gbe gbominira ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Wọn ni ẹni ti yoo royin ogun ko ni i ku sogun, ọrọ yii gan-an lo ṣẹ mọ oyinbo Chinese kan, Pengchao Zang, tawọn agbebọn ji gbe ni otẹẹli kan lagbegbe Ẹyẹnkọrin, nijọba ibilẹ Aṣà, ni Kwara, lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, to si wa lakata wọn fun ọjọ mẹsan-an, ṣugbọn to gbominira laaarọ kutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, DSP, Ejirẹ Adetoun Adeyẹmi, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin wa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ogunjọ, oṣu Kẹta yii. O ni pẹlu akitiyan awọn ẹṣọ alaabo, iyẹn ọlọpaa ati fijilante, awọn ti doola ẹmi Williams Zang, to si ti darapọ mọ mọlẹbi rẹ layọ ati alaafia.

O tẹsiwaju pe lọjọ kẹwaa, oṣu Kẹta yii, ni awọn agbebọn mẹfa kan ya wọ otẹẹli kan ti wọn n pe ni Cherish Guest House, lagbegbe Ẹyẹnkọrin, nibi ti oyinbo yii ti n jaye ori ẹ, ti wọn si ji i gbe lọ. Ṣugbọn nigba ti ọlọpaa ati fijilante n wa wọn kiri ni wọn kan wọn ninu igbo, ti wọn si doola ọmọ orileede China ọhun, to si ti darapọ awọn mọlẹbi rẹ lai fara pa.

Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, Victor Ọlaiya, ti ni gbogbo awọn to huwa ibajẹ naa ko ni i lọ lai jiya. Bakan naa lo rọ gbogbo awọn olugbe Kwara, ki wọn maa wa ni oju ni alakan fi n ṣọri, ati pe wọn ba sakiyesi iwa aitọ lagbegbe wọn, ki wọn fi to awọn ẹṣọ alaabo leti.

 

Leave a Reply