Aderounmu Kazeem
Wahala nla lo ṣẹlẹ lọjọ Aje, Mọnde, ana nibi ti awọn aṣaaju ilẹ Hausa kan ti kora wọn jọ niluu Kaduna lati sọrọ lori eto aabo, ṣugbọn ti awọn janduku kan kọlu wọn, ti wọn si da ipade apero ọhun ru.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ, nibi ti ẹgbẹ kan to jẹ akojọpọ oriṣiriiṣi ẹgbẹ nilẹ Hausa, Coalition of Northern Groups (CNG) pe ipade apero si lati sọrọ lori bi eto aabo yoo ti ṣe wa loke ọya lawọn janduku kan ti lọọ kọlu wọn.
Wọn ni bi wọn ti ṣe ba mọto jẹ, bẹẹ ni wọn ṣe awọn eeyan leṣe, ti wọn tun da ipade ọhun ru pẹlu, ti ọpọ eeyan si gbe apa oriṣiriiṣi lọ sile wọn.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Abdul-Azeez Suleiman sọ pe awọn to waa kọlu awọn le ni ọgọrun-un nile kan ti wọn n pe ni Arewa House ni Kaduna.
Ọkunrin yii sọ pe koko ipade naa ni lati wa bi aj̀ọṣepọ yoo ṣe wa laarin awọn araalu atawọn ẹsọ oloogun lati le wa eto alaafia ti yoo fẹsẹ rinlẹ fawọn eeyan loke Ọya. O ni lara awọn ti wọn wa nibi ipade ọhun ni ẹṣọ agbofinro ti wọn ti fẹyinti lẹnu iṣe atawọn ọba alaye, awọn obinrin, awọn ọdọ ati ẹgbẹ oniṣowo loriṣiriiṣi.
O fi kun un pe bi ipade ọhun ṣe fẹẹ bẹrẹ lawọn eeyan ọhun ya de, lẹyin ti wọn ti kọlu awọn ẹsọ to n ṣọ oju ̀ọna. O ni bi wọn ṣe n ju aga ijokoo, bẹẹ ni wọn n fọ gilaasi, ti wọn si ṣe awọn eeyan rẹpẹtẹ leṣe, ti wọn si tun ba awọn mọto tawọn eeyan gbe wa sibi pade ọhun jẹ paapaa.
Ọkunrin agbẹnusọ yii sọ pe ohun ibanujẹ ni bi awọn janduku ṣe le maa rin nigboro lọsan-an gangan, ti ko si sẹni kankan to le da wọn lọwọ kọ. O ni ohun ti oun mọ daju ni pe awọn eeyan kan ti wọn wa nipo agbara n ri nnkankan gba ninu bi wahala awọn janduku ṣe gbilẹ loke ọya, ati pe awọn eeyan naa ko dẹkun lati ri i pe wahala to n ṣelẹ ọhun ko dawọ duro rara.
O ni lẹyin wakati meji tawọn janduku ọhun ti lọ tan lawọn ẹṣọ agbofinro too de.O waa ṣeleri wi pe gbogbo ọna to yẹ ni ẹgbẹ awọn yoo gba lati ri i pe eto alaafia to peye pada si oke-ọya ni Naijiria.