Awọn kan n lepa ẹmi mi nitori aṣiri iwe-ẹri Ademọla Adeleke ti mo tu-Adeyi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ ilẹ wa tẹlẹ, to tun jẹ ọkan pataki ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Akin Adeyi, ti kegbajare si ọga ọlọpaa ẹkun kọkanla (Zone X1) lati gba a lọwọ awọn ọmọlẹyin Gomina Ademọla Adeleke ti wọn n lepa ẹmi rẹ.

Laarin oru ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, si ọjọ Abamẹta, Satide, lawọn janduku ati ọkunrin oloṣelu ẹgbẹ PDP kan gbe katakata, ti wọn si lọọ wo ileetura ti Adeyi ni sagbegbe Ting road, niluu Oṣogbo, tịpilẹtipilẹ pẹlu iranlọwọ awọn ti wọn wọ aṣọ ọlọpaa.

Ninu lẹta ‘ẹ gba mi’ ti Adeyi kọ si ọga ọlọpaa naa, to si fi ẹda rẹ ranṣẹ si ajọ DSS, lo ti ṣalaye pe igba keji niyi ti oun yoo kegbajare lori idunkooko mọ ẹmi rẹ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “O pọn dandan fun mi lati kọ lẹta yii fungba keji ninu ọdun keji, latari oniruuru ikọlu ati idunkooko mọ ni ti awọn kan n ṣe si mi nipinlẹ yii.

“Otitọ to wa nibẹ ni pe mo gbe igbesẹ ti ko kọja ẹtọ ti mo ni gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP lọdun 2021, nigba ti mo lọ sọdọ igbimọ to n ṣayẹwo awọn oludije funpo gomina nigba naa nipa awọn iwe-ẹri ti Sẹnetọ Ademọla Adeleke ko kalẹ.

“Awọn igbimọ naa gba pe loootọ ni oniruuru aṣiṣe ati jibiti wa ninu awọn iwe-ẹri naa. Awọn igbimọ naa dupẹ lọwọ mi, wọn si paṣẹ pe ki ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ọṣun ati awọn alatilẹyin oludije naa ṣiṣẹ lori awọn dọkumẹnti ọhun ko too di pe wọn yoo ko o kalẹ fun ajọ INEC.

“Latigba yẹn ni n ko ti le fi ẹdọ leri oronro mọ, ti mo si tete fi ọrọ naa to ileeṣẹ ọlọpaa, DSS, awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun atawọn ọmọ orileede yii leti.

“Sibẹ, awọn ẹniibi yii ko dẹyin lẹyin mi, ṣugbọn mo pinnu lati dakẹ lori ẹ titi di asiko yii ti awuyewuye tun ṣu yọ lori ọrọ iwe-ẹri gomina.

“Oru ọjọ Satide ni wọn lọọ fi katakata wo ileeṣẹ mi. Ori pilọọti ilẹ mẹrin ni ileegbafẹ mi wa, ọkẹ aimọye miliọnu Naira lo si gbe ibẹ duro.

“Ẹmi mi wa ninu ewu gidigidi, idi niyi tu mo fi n parọwa si ileeṣẹ ọlọpaa ati ajọ DSS lati gba ẹjọ mi ro, ki wọn ṣaanu ẹmi emi atawọn mọlẹbi mi”.

 

Leave a Reply