Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni awọn mẹfa kan foju ba ile-ẹjọ Majisreeti agba to wa niluu Ado-Ekiti, lori ẹsun idaluru, iwọde ti ko ba ofin mu ati dida rogbodiyan silẹ.
Awọn eeyan ọhun ni Adebayọ Temitọpẹ, ẹni ọdun mejilelọgbọn; Ibrahim Musau, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn; Eze Oluwabunmi, ẹni ọdun mejilelọgbọn; Ogunlusi Abiọdun, ẹni ogun ọdun; Arowoṣẹgbẹ Esther, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn; ati Peter Joy, ẹni ọdun mọkanlelogun.
Agbẹnusọ ọlọpaa, Caleb Leramo, sọ fun kootu pe ọgunjọ, oṣu to kọja, lawọn olujẹjọ huwa ọhun niluu Ikọle-Ekiti pẹlu bi wọn ṣe kọlu sẹkiteriati ijọba ibilẹ naa, ti wọn si fọ gilaasi, bẹẹ ni wọn ba ọkọ marun-un jẹ, eyi to jẹ dukia ijọba ipinlẹ Ekiti.
O ni ṣe lawọn eeyan naa tun ko ara wọn jọ, ti wọn si n dukooko lati da ibẹrubojo sawọn eeyan ilu naa lara.
O waa ni awọn iwa naa lodi si ofin iwa ọdaran tipinlẹ Ekiti ṣagbekalẹ lọdun 2012, iyẹn abala kọkanlelaaadọrin (71) ati irinwo-le-mọkanlelaaadọta (451).
Nigba ti wọn ka awọn ẹsun wọnyi si awọn afurasi ọhun leti, wọn ni awọn ko jẹbi. Amofin Gbenga Ariyibi ati Amofin Victoria Adelu si bẹbẹ fun beeli wọn lọna irọrun, bẹẹ ni wọn sọ pe akoba lọrọ naa, awọn onibaara awọn ko huwa ti wọn tori ẹ dero ile-ẹjọ.
Majisreeti-agba Abdulhamid gba beeli ẹni kọọkan awọn olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (N100,000) ati oniduuro kọọkan to ni ile ti wọn le wa a si.
Igbẹjọ yoo bẹrẹ lọjọ kẹsan-an, oṣu kejila, ọdun yii.