Awọn meje foju bale-ẹjọ l’Akurẹ, nnkan ija oloro ni wọn ka mọ wọn lọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Nile-ẹjọ Majisireeti to kan to wa niluu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, ni awọn meje kan ti n jẹjọ bayii, lẹyin ti ọwọ tẹ wọn pẹlu ọpọlọpọ awọn nnkan ija oloro niluu Ọwọ.

Awọn olujẹjọ ọhun ni: Balogun Samuel, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, Sule Ojo, ọmọ ọgbọn ọdun, Amọdu Emmanuel, ẹni ọdun mọkanlelaaadọta, Ṣẹgun Ọmọtoyinbo, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, Ajayi Adejumọ, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn Jamiu Aliu ati Ọlasọji Francis, ti wọn jẹ ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu Itunu Ọsọbu, to jẹ agbefọba pe ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ aarọ ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, lọwọ awọn ṣọja to n ṣe ayẹwo awọn ọkọ loju ọna Ọwọ si Ikarẹ, tẹ awọn afurasi naa pẹlu ibọn, aake, ada loriṣiiriṣii, ọbẹ, oolu atawọn nnkan ija oloro mi-in.

O ni ṣe ni wọn ko awọn nnkan ija wọnyi pamọ sinu ọkọ ti wọn wa, ti wọn si ro pe ko si ẹṣọ alaabo to le ri wọn.

Lẹyin ti awọn ṣọja ti da wọn duro si ọdọ wọn fun igba diẹ lo ni wọn ṣẹṣẹ waa fa wọn le ọlọpaa lọwọ ko too di pe awọn ko wọn wa sile-ẹjọ lẹyin ọpọlọpọ iwadii ti awọn ti ṣe lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ọsọbu ni ko si ani-ani pe awọn olujẹjọ mejeeje ti ṣẹ si abala karun-un ninu akanṣe iwe ofin Naijiria ti ọdun 2004, eyi to ta ko ṣiṣe amulo awọn nnkan ija oloro lọna to lodi sofin.

Agbefọba ọhun ni oun fẹ ki ile-ẹjọ paṣẹ ki wọn ṣi fi awọn olujẹjọ naa pamọ sinu ọgba ẹwọn titi digba ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Agbẹjọro awọn olujẹjọ ninu ọrọ tirẹ ta ko aba yii, o ni ile-ẹjọ gbọdọ fun awọn onibaara oun laaye ọjọ diẹ ki wọn fi fesi lori ẹbẹ agbefọba gẹgẹ bii ilana ofin.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ W. O Dosumu, ni ki awọn olujẹjọ ọhun ṣi wa latimọle ọlọpaa titi di ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta ọdun yii.

Leave a Reply