Ọmọ ọran kan ree o, nitori ẹgbẹrun mẹrindinlogun Naira, o ṣa iya to bi iya ẹ pa

Adewale Adeoye

Ọmọ ọran ni orukọ ti wọn iba maa pe ọmọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Nkereuwem Umoren Ekpo, to n gbe lagbegbe Adiasim Ikot-Udo, nijọba ibilẹ Essien-Udim, to fada ṣa iya rẹ agba, Martina Udoudo Akpan, ẹni ọdun aadọrun-un ọdun nitori ẹgbẹrun mẹrindinlogun ataabọ Naira.

ALAROYE gbọ pe inu oko ẹgẹ ti wọn da ni ọmọkunrin yii ati iya rẹ agba yii wa  ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ti wọn n ṣiṣẹ lọwọ, Ṣugbọn lojiji ni Ekpo fa ada oloju meji ti wọn fi n ṣiṣẹ yọ, lo ba bẹrẹ si i ṣa iya agbalagba naa. O si ṣe bẹẹ ṣa a yannayanaa titi ti ẹmi fi bọ lara rẹ lọjọ naa. Nigba to ri i pe iya naa ti ku lo ba tu ẹgbẹrun mẹrindinlogun Naira kan to wa leti aṣọ rẹ, o si sa lọ.

Oga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, C.P Waheed Ayilara, to ṣafihan awọn ọdaran tọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ naa tẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, sọ pe ọwọ pada tẹ Ekpo, nibi to sa pamọ si, tawọn ọlọpaa si fi kele ofin mu un.

O ni, ‘‘Ọdọ wa ni Ekpo wa bayii, o ti jẹwọ fawọn agbofinro bo ṣe pa iya agba rẹ, ọkan lara awọn ada oloju meji ti wọn n lo loko lọjọ naa lo fi ṣa oloogbe naa pa ko too di pe o ji owo ẹti aṣọ rẹ, oun paapaa si ti n kabaamọ bayii’’.

Ọga ọlọpaa ọhun ni awọn maa too foju afurasi ọdaran yii bale-ẹjọ tawọn ba ti pari iwadii tawọn n ṣe lori ọrọ rẹ.

Leave a Reply