Awọn meji ku sinu kanga ti wọn n gbẹ l’Abẹokuta

Adewale Adeoye

Meji lara awọn ọmọ orileede Benin kan, Avade Clement ati Oloogbe Achefon Edua, ti wọn n gbe nilẹ wa, ti wọn yan iṣẹ gbigbẹ kanga laayo ti pade iku ojiji nibi ti wọn ti n ṣiṣẹ oojọ wọn lagbegbe Laderin, nijọba ibilẹ Abẹokuta South, nipinlẹ Ogun, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

ALAROYE gbọ pe Ọgbẹni Akinsanya Ganiyu lo gbeṣẹ pe ki wọn b’oun gbẹ kanga kan sinu ọgba ile titun kan to n kọ lọwọ fun wọn. Ẹnu iṣẹ naa ni wọn wa ti nnkan fi yiwọ, ooru inu kanga naa lo ṣeku pa wọn, kawọn eeyan si too mọ ohun to n ṣẹlẹ lati le sugbaa wọn, ẹlẹkọ ọrun ti polowo fun awọn mejeeji, wọn ti dagbere faye.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ọdun yii, sọ pe Akinsanya to gbeṣẹ ọhun fawọn ajoji naa lo sare lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa agbegbe naa leti, ti DPO teṣan naa si ran awọn ọmọọṣẹ rẹ kan lọ sibi iṣẹlẹ naa. Awọn ọlọpaa naa ni wọn gbe oku awọn oloogbe ọhun jade pẹlu iranlọwọ awọn araalu kan.

Dokita ileewosan kan to wa lagbegbe Ijaye, ti wọn gbe wọn lọ lo fidi rẹ mulẹ pe oku wọn ni wọn gbe wa.

Wọn ti gbe oku awọn oloogbe naa pada siluu wọn ti i ṣe orileede Benin.

Leave a Reply