Awọn ọlọkada l’ọmọkunrin yii maa n pa, ti yoo si ji ọkada wọn gbe lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tun tu aṣiri mi-in nipa ọmọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Dọlapọ Babalọla, ẹni tọwọ tẹ nipari oṣu Kẹta, ọdun yii, lẹyin to pa ọlọkada kan to jẹ ọrẹ timọtimọ rẹ, to si bo oku rẹ mọlẹ ninu igbo kan niluu Oke-Igbo, ko too gbe ọkada rẹ sa lọ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Abayọmi Ọladipọ ṣalaye fawọn oniroyin lasiko to ṣafihan awọn afurasi ọdaran kan lolu ileeṣẹ wọn to wa loju ọna Igbatoro, Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, pe o kere tan, awọn ọlọkada mẹrin mi-in ni Babalọla ti pa nipakupa kaakiri awọn agbegbe kan ko too pa ọrẹ rẹ, Ẹfanjẹliisi Ọpẹyẹmi Oyelakin, eyi to pada tu u laṣiiri.

O ni awọn meji ni wọn pade iku ojiji lati ọwọ Babalọla ninu oṣu Kẹta, ọdun 2023, o pa ẹni kan lagbegbe Kabba, nipinlẹ Kogi, to si tun pa ẹni keji loju ọna Ileṣa si Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun. Bo ṣe pa awọn ọlọkada ọhun tan lo ni o ge awọn ẹya ara wọn kan, eyi to lọọ fi ṣetutu ọla.

Ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii kan naa lo ni o tun pa ọlọkada mi-in niluu Ondo, to si lọọ ju oku rẹ sinu igbo kan lagbegbe Òbòtò, lagbegbe Bọlọrunduro, eyi to wa loju ọna marosẹ Ondo si Akurẹ.

Oṣu Kẹwaa, ọdun 2023, lo ni ọdaju apaayan ọhun ati ẹnikan ti wọn n pe ni Sikiru Mutiu, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ S.K, tan ọlọkada mi-in, Joel Ọlagoke, ẹni ti wọn lo jẹ ọrẹ ati kekere fun Babalọla, lọ sinu igbo kan nitosi Ondo, nibi ti wọn pa a si, wọn kun ẹya ara rẹ bii ẹni kun ẹran, eyi ti wọn lọọ ko fun awọn babalawo kan, Mujeeb Lawal ati Ṣina Ojo.

Ọladipọ ni ọwọ awọn ti tẹ awọn babalawo mejeeji pẹlu awọn mẹta mi-in, Ọlatunji Toheeb, Ayegbajẹjẹ Michael ati Ọlayinka Abiọla, ti wọn lo ra ọkada ti Babalọla ja gba lọwọ Ọlagoke lọwọ rẹ.

Meje ninu awọn ọkada ọlọkada ti Babalọla atawọn ẹmẹwa rẹ ninu iwa ọdaran ji gbe lo ni awọn ti ri gba pada nibi ti wọn ta wọn si, to si ku afurasi kan ti wọn ṣi n wa lori iṣẹlẹ naa.

Ninu alaye ti Lawal ṣe fun akọroyin wa to fọrọ wa a lẹnu wo, o ni iṣẹ ọdẹ ati babalawo loun yan laayo niluu Ondom ti oun n gbe.

O ni ọlọpaa kan to porukọ ara rẹ ni Dọlapọ, lo waa ba oun ninu oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, pe oun ri ẹran ara eeyan kan nibi ijamba ọkọ, ti oun si fẹ ki oun ba oun fi kinni ọhun ṣe oogun owo.

Nigba ta a beere lọwọ rẹ bo ṣe mọ bi wọn ti n fi ẹran ara eeyan ṣoogun owo, alaye to ṣe fun wa ni pe inu iwe loun ti ka nipa rẹ.

Lawal ni funra Dalapọ lo gun ẹran eeyan to mu wa ọhun pẹlu ewe kan ti oun fun un ninu odo, ki oun too ba a fi i ṣe ohun to fẹẹ lo o fun.

O ni lọjọ kan loun tun ṣe alabaapade oku kan ninu igbo, nibi ti oun ti n ṣe ọdẹ lagbegbe Ita-Nla, niluu Ondo, nigba ti oun si bun ọrẹ oun ti wọn n pe ni Oluwo gbọ nipa rẹ, oun lo bẹ oun pe ki oun ba oun ge ori oku naa wa nigbakuugba ti oun ba ti pada lọ ti oun si ṣe bẹẹ.

Abiọla ninu ọrọ tirẹ ni ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, loun n gbe, o ni loootọ loun n ra ọkada lọwọ Dọlapọ, bo tilẹ jẹ pe oun mọ pe ọja ole lo n ta fun oun.

Ẹgbẹrun lọna ọgọjọ Naira (#160, 000) lo ni oun ra ọkada TVS ti oun ra gbẹyin lọwọ rẹ, o ni ṣe lo waa gbe ọkada naa pade oun ni Ile-Ifẹ, nipinlẹ Ọṣun.

Abiọla waa bẹ ijọba pe ki wọn ṣiju aanu wo oun, nitori oun ko tun jẹ dan iru iwa bẹẹ wo mọ ti oun ba fi bọ ninu eyi ti oun wa yii.

Leave a Reply