Awọn mejila fẹwọn jura l’Ekoo, okoowo epo diisu ni wọn n ṣe lai gba’ṣẹ

Faith Adebọla, Eko

Ile-ẹjọ giga tijọba apapọ to fikalẹ siluu Ikẹja, l’Ekoo, ti ni ki awọn eeyan mejila kan maa lọ si ọgba ẹwọn Kirikiri l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, latari ẹsun pe wọn n ṣe owo epo diisu lai gba aṣẹ.

Awọn tọrọ kan ni Ọdẹnikẹ Rasaq, Oluwafẹmi James, Ọjajuni Adebọwale, Dele Napoleon, Aderẹmi Akinade, Stephen Ogunboye, Ekene Okendu, Agbanoma John, Azu Okengwu, Alum Julius, Awah Ucheojo ati Neele Keerebari.

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati inakunaa nilẹ wa, EFCC, lo wọ awọn mejila yii dele-ẹjọ. Wọn tun darukọ ọkọ oju-omi kan, MT Mother Comfort, ati ileeṣẹ ti wọn ti n ṣiṣẹ, Azamosa Limited, niwaju adajọ.

Ọjọ kejila, oṣu keje, ọdun yii, lawọn afurasi ọdaran yii huwa to lodi sofin ọhun gẹgẹ bi agbẹjọro fun olupẹjọ, Ọgbẹni Idris Mohammed, ṣe wi. O ni ẹsun ti wọn fi kan wọn ta ko isọri kẹta, abala kẹta, iwe ofin ẹsun oriṣiiriṣii ti ọdun 2004, ijiya to lagbara lo si wa fun iru ẹsun yii labẹ isọri kin-in-ni, abala kẹtadinlogun, iwe ofin naa.

Wọn bi awọn olujẹjọ naa pe ki lero wọn lori ẹsun ti wọn fi kan wọn, gbogbo wọn lawọn ko jẹbi rara. Lọọya wọn, Ṣọla Ọbabinrin, rawọ ẹbẹ sile-ẹjọ naa pe ki wọn faaye beeli silẹ fawọn onibaara oun.

Adajọ Muslim Hassan faaye beeli silẹ pẹlu miliọnu mẹwaa naira fun ẹnikọọkan, pẹlu ẹlẹrii kan ni iye owo kan naa fun ọkọọkan wọn.

Nitori ko ṣee ṣe fun wọn lati pese ohun tile-ẹjọ beere fun yii ladajọ ṣe paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ sọgba ẹwọn, wọn si maa wa nibẹ titi ọjọ kẹrin, oṣu keji, ọdun to n bọ, ti wọn sun igbẹjọ to kan si.

Leave a Reply