Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Onidaajọ John Adeyẹye tile-ẹjọ giga ilu Ado-Ekiti ti ṣedajọ ẹwọn ọdun mẹrinla fawọn mẹta kan lori ẹsun igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi, nini ibọn nikaawọ ati igbiyanju lati digun jale.
Okon Joseph, ẹni ọdun mẹtalelogun, pẹlu Ebele Sunday toun jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun ati Daniel Simon, ẹni ogun ọdun, ni adajọ naa sọ sẹwọn ọdun mẹrinla fun ẹsun akọkọ, ọdun mẹwaa fun ẹsun keji, ati ọdun mẹrinla fun ẹsun kẹta.
Gẹgẹ bi ẹjọ naa ṣe lọ, awọn ọlọpaa fidi ẹ mulẹ pe ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 2018, lawọn ọdaran naa huwa yii nigba ti wọn duro soju titi marosẹ niluu Emure-Ekiti, pẹlu ibọn ibilẹ meji, ti wọn si ni erongba lati digun ja awọn to ba kọja lole.
Wọn ni awọn eeyan agbegbe naa lo ta awọn ẹṣọ alaabo lolobo ti wọn fi lọọ ka wọn mọ ibi ti wọn duro si, eyi to jẹ agbegbe kan laarin Emure si Eporo, wọn si ba awọn nnkan to ṣakoba fun wọn lọwọ wọn.
Awọn ẹsun yii ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe wọn ta ko abala kẹfa ati ẹkẹta iwe ofin to gbogun ti idigunjale, eyi tijọba Naijiria ṣagbekalẹ lọdun 2004.
Lasiko ti ẹjọ naa n lọ lọwọ, Amofin O.M Ajumọbi pe ẹlẹrii mẹrin lati rojọ ta ko awọn olujẹjọ, bẹẹ lo ko ibọn meji, ọta ibọn mẹta, oogun oloro atawọn nnkan mi-in kalẹ gẹgẹ bii ẹri.
Amofin Chris Omokhafe lo ṣoju Ebele atawọn meji to ku, bẹẹ ni ko pe ẹlẹrii kankan.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, Onidaajọ Adeyẹye ni ko yẹ ki iru awọn eeyan bii tawọn ọdaran ọhun wa lawujọ ki wọn ma baa ṣe awọn eeyan nijamba, eyi lo si fi dajọ ẹwọn fun wọn lori ẹsun kọọkan. O waa ni ẹẹkan naa ni wọn yoo ṣẹwọn ọhun, eyi to tumọ si pe ọdun mẹrinla ni wọn yoo lo.