Awọn oṣiṣẹ kootu bẹrẹ iyanṣẹlodi nipinlẹ Ọyọ, wọn nijọba n pẹ ko too sanwo oṣu awọn

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gbogbo ilẹkun abawọle si awọn ile-ẹjọ to jẹ tijọba ipinlẹ Ọyọ lo wa ni titi pa bayii nitori ti awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ ti bẹrẹ iyanṣẹlodi.

Iyanṣẹlodi ọhun to bẹrẹ lọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yii, ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lo waye nitori bi ijọba ipinlẹ naa ko ṣe ti i san owo-oṣu wọn fun oṣu Keje to pari ni ijẹrin ode yii.

Nigba to n sọrọ lori igbesẹ naa, Alukoro fun ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ nipinlẹ yii, Ọgbẹni Ọbafunṣọ Okulaja, sọ pe ninu ipade ti ẹgbẹ ‘Judiciary Staff Union of Nigeria’ (JUSUN), iyẹn, ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ nipinlẹ Ọyọ, ṣe lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ko too di pe oṣu Keje pari gan-an lawọn ti pinnu pe bi ijọba ko ba fi sanwo oṣu Keje fawọn titi ti oṣu naa fi pari, niṣe lawọn yoo kan fọwọ lẹran ti awọn yoo maa wo iṣẹ niran

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Okulajaṣe sọ, “Oṣu Keje ti pari, awọn eeyan wa ko si rowo wọ mọto wa sibi iṣẹ, nitori ẹ la ṣe kuku sọ pe ki kaluku wọn jokoo sile wọn.

“Ki i ṣe bi ijọba ṣe maa n pẹẹ sanwo oṣu fun gbogbo oṣiṣẹ ipinlẹ yii ree. Lati ọjọ kẹẹẹdọgbọn (25), oṣu, ni wọn ti maa n sanwo awọn oṣiṣẹ ẹka yooku, bi oṣu ko ba ti i pari patapata tabi ki oṣu mi-in bẹrẹ, wọn ki i sanwo fawa ni tiwa.

“Ki i ṣe pe wọn ṣẹṣẹ n ṣe bẹẹ fun wa o, lati ọdun 2021 ni wọn ti maa n ṣe bẹẹ fun wa.

“Ti ijọba ba le maa fi awọn oṣiṣẹ ẹka alaṣẹ atawọn oṣiṣẹ ẹka aṣofin ṣọkan, o yẹ ki wọn le ṣe bẹẹ fawa naa nitori awa naa lẹka to ṣikẹta ẹka mejeeji ninu eto iṣejọba”.

Titi di ba a ṣe n kọroyin yii ni gbogbo ilẹkun abawọle kootu gbogbo to jẹ ti ipinlẹ Ọyọ wa ni titi pa nitori eto iyanṣẹlodi wọn naa.

Leave a Reply