Awọn ọba alaye ṣewọde l’Ekiti, nitori ijọba ibilẹ tuntun ti Fayemi gbe kuro lọdọ wọn

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ko din ni kabiyesi meje lati ijọba ibilẹ Ikọle, nipinlẹ Ekiti, ti wọn jade fẹhonu han lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii, nitori ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ekiti ti Gomina Kayọde Fayẹmi ṣẹṣẹ da silẹ, to si gbe e si ilu Ijẹṣa-Iṣu Ekiti.

Awọn kabiyesi yii ati awọn ọmọ ilu wọn ni wọn kora jọ siluu Asin-Ekiti, nibi ti wọn ti sọ pe ki Gomina Fayẹmi da ijọba ibilẹ naa pada si ilu Usin-Ekiti to ti kọkọ kede rẹ pe oun yoo gbe e si, ko too gbe e lọ Ijẹṣa-Iṣu bayii.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹfa, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 yii, ni Gomina Kayọde Fayẹmi kede idasilẹ ijọba ibilẹ tuntun, eyi tijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ikọle wa lara wọn, to si ni Usin-Ekiti ni yoo wa.

Ṣugbọn lẹyin oṣu kan ti gomina ṣe ikede yii ni wọn yi i pada, ti wọn si gbe e lọ si Ijẹṣa-Iṣu, ti wọn si tun kede Ajẹlẹ tuntun fun ijọba ibilẹ naa.

Eyi lo fa a tawọn ọba ilu to wa labẹ ijọba ibilẹ tuntun naa ṣe fẹhonu han.

 

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Olotunja ti ilu Otunja-Ekiti, Ọba Adedeji Fagbamila, to sọrọ lorukọ awọn ọba yooku dupẹ lọwọ awọn ọmọ ilu wọnyi bi wọn ṣe jade lọpọ yanturu lati darapọ mọ iwọde yii, ati bi wọn ṣe ṣe e ni irọwọ-rọsẹ.

Olotunja sọ pe awọn ori ade mejeeje to jade fun iwọde yii ṣe bẹẹ lati ja fun ẹtọ wọn ni, ati lati ja fun ọjọ iwaju awọn ọmọ ilu wọn, ki wọn le gba ominira labẹ awọn ilu mi-in to wa ni agbegbe naa.

Awọn ọba yii rọ Fayẹmi pe ko yi ipinnu rẹ pada, ko si da ijọba ibilẹ naa pada si ilu Usin-Ekiti, nibi ti won ti kọkọ kede rẹ ṣaaju.

“Awa kabiyesi wọnyi fẹẹ fi da ijọba ipinlẹ Ekiti lsoju pe aṣiṣe ni igbesẹ ti wọn gbe yii, ipinnu wọn yii ko si le fẹṣẹ mulẹ. Nitori awa ilu wọnyi ko ni i gba ki aṣẹ naa mulẹ”

Bakan naa ni ọkunrin kan, Lanre Ayejuyọ, to sọrọ lorukọ awọn ọmọ ilu yooku sọ pe awọn alagbara kan nipinlẹ Ekiti lo wa nidii bijọba ṣe yi ohun pada lori ohun ti wọn fẹẹ ṣe tẹlẹ si Usin-Ekiti. O ni ayipada ipinnu yii ko tumọ si nnkan mi-in ju aiṣootọ ati ododo ninu iṣejọba ipinlẹ Ekiti lọ, nitori wọn ti tẹ ẹtọ awọn ilu mejeeje to n fẹhonu han yii mọlẹ

” Mo gbagbọ pe Gomina Kayọde Fayẹmi ko mọ nnkan kan nipa igbesẹ yii. Ṣugbọn a bẹ Dokita Kayọde Fayẹmi ati alaga igbimọ naa ki wọn ba wa yi ipinnu yii pada.

Leave a Reply