Awọn ọdọ ilẹ Hausa lawọn fara mọ ki Ọṣinbajo di aarẹ ni 2023

Adefunkẹ Adebiyi

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ karun-un, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, ni awọn ọdọ kan lati awọn ipinlẹ ilẹ Hausa mọkandinlogun to wa ni Naijiria, kora wọn jọ si Kaduna, nibẹ ni wọn ti ṣepade kan, ti wọn si fẹnu ko pe awọn fara mọ Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lati di aarẹ Naijiria ni 2023.

Nibi ipade naa ti wọn pe akọle ẹ ni ‘Nothern Agenda: our real solution’ ni wọn ti ṣalaye pe ko sohun to dara fun Naijiria lọdun 2023 ju ki wọn jẹ ki Yoruba di aarẹ lọ.

Wọn si ni ko yẹ kẹnikẹni tun maa wa ondije dupo kan kiri mọ, bi ko ṣe pe ki wọn fẹnu ko si yiyan Ọjọgbọn Yẹmi Ọsinbajo ti i ṣe Igbakeji aarẹ wa lọwọlọwọ. Wọn ni ọkurin naa ni oye lori lati tukọ Naijiria, yoo si gbe orilẹ-ede yii de ebute ogo nipa ṣiṣẹgun rogbodiyan awọn afẹmiṣofo ati oriṣiiriṣii iṣoro ti orilẹ-ede yii n koju.

Wọn ni Ọṣinbajo yoo kapa ija ẹṣin ati ẹlẹyamẹya, apa Arewa paapaa yoo si ni alaafia ju bo ti ṣe wa lọ.

Bakan naa lawọn ọdọ ilẹ Hausa ọhun sọ pe ero tawọn kan n ro pe ilẹ Hausa ni agbara yoo tun duro si lọdun 2023 ko le ṣe Oke-ọya ni anfaani kankan. Wọn ni iru ero bẹẹ le da wahala silẹ, bi Naijiria ba si fi kọ ti wọn ko jẹ ki Ọsibanjo di aarẹ ni 2023, atubọtan rẹ maa lagbara gidi.

Bakan naa lawọn ọdọ yii sọ pe awọn lodi si pe ki aarẹ ati igbakeji rẹ jẹ ẹlẹsin kan naa. Wọn ni ohun to daa ni pe ki ẹsin wọn yatọ, bi ẹni kan ba jẹ Kristiẹni, ki ẹni keji si jẹ Musulumi.

Olori ẹgbẹ Arewa Consensus Assembly, Daniel Shawaulu atawọn yooku ẹ bii Alaaji Suleiman Makama ati Alaaji Khalid Mohammad ni wọn buwọ lu ohun tawọn ọdọ naa fẹnuko si yii.

Leave a Reply