Awọn oloṣo yari o, wọn lawọn o ni i fun awọn oni taxi ni ‘kinni’ ṣe fodidi ọsẹ kan

Ọlọrun nikan lo mọ ibi ti awọn dẹrẹba to n wa tasin ni adugbo kan ti wọn n pe ni Momboso, ni orileede Kenya, yoo gbe ọrọ wọn gba bayii ti wọn ba fẹẹ tura. Afimọ ki wọn ma ta luusi lọdọ awọn aṣẹwo pẹlu bi awọn oloṣo naa ṣe ni awọn ko ni i fun wọn ni ‘kinni’ ṣe mọ fun odidi ọsẹ kan. Wọn lawọn maa fi ‘kinni’ awọn da wọn lara, awọn yoo fi da wọn loju.

Bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe orileeede Naijiria nisẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, yoo jẹ ẹkọ fun awọn dẹrẹba Naijiria to ṣee ṣe ki wọn fẹẹ hu iru iwa bẹẹ.

Ohun ta a ri gbọ ni pe inu n bi awọn oloṣo si awọn dẹrẹba mọto naa, wọn ni odidi ọsẹ kan gbako ni wọn ko fi ni i tọ kinni awọn to maa n dun mọ wọn naa wo.

Nibi tọrọ naa ka wọn lara de, wọn ti fofin lelẹ o, pe ẹnikẹni to ba ṣe yunkunyunkun fun awọn eeyan agbegbe naa ninu ẹgbẹ awọn oloṣo tawọn ba gba wọn mu, o ti kuro lọmọ ẹgbẹ awọn lati asiko naa lọ niyẹn.

Wọn ni bo tilẹ jẹ pe ọna kan ṣoṣo tawọn n gba ri owo ti awọn fi n bọ ọmọ ati mọlẹbi awọn naa ni iṣẹ oloṣo yii, sibẹ, awọn yoo sẹ ara awọn, nitori ẹlẹgbẹ awọn tawọn fẹẹ ja fun yii.

Njẹ ki lo fa sababi tawọn oloṣo fi binu tan, wọn ni ọrọ naa ko sẹyin bi wọn ṣe ni awọn dẹrẹba bii mẹrindinlogun ja obinrin ajeji toun naa n wa mọto lole owo, ti wọn si tun ja a lole ara lọjọ Ẹti, Furaidee, to lọ yii, nibi kan ti wọn n pe ni Forest Road, ni Nairobi.

Eeyan mẹrindinlogun la gbọ pe wọn mu lori iṣẹlẹ naa, odidi ọjọ mẹẹẹdogun ni wọn si fi ti wọn mọle ki wọn le ṣe iwadii kikun lori iṣẹlẹ buruku naa gẹgẹ bi tẹlifiṣan orileede Kẹnya kan, K24tv, ṣe sọ.

Ọmọbinrin ajeji kan to wa lati ilẹ Zimbabwe ni wọn ni awọn eeyan naa kọ lu lọjọ kẹrin, oṣu Kẹta, ọdun yii, ti aworan iṣẹlẹ yii si gba gbogbo ori ẹrọ ayelujara kan. Obinrin naa lọọ fẹjọ wọn sun ni teṣan ọlọpaa Parkland, ni Nairobi.

Oludari ẹgbẹ to si n ri si ẹtọ awọn aṣẹwo, Maryline Laini, sọ pe loootọ, onibaara awọn ni awọn awakọ tasin yii, ṣugbọn awọn ko le laju awọn silẹ ki wọn maa ri obinrin fin tabi ki wọn maa fi ẹtọ rẹ du u, ki wọn si maa fipa ba a lo pọ.

O ni bi awọn ṣe fẹẹ fi ibalopọ du awọn ọkunrin to n wa tasin yii

niluu naa jẹ ọna kan lati beere fun idajọ ododo ati lati fopin si ki wọn maa foju awọn obinrin gbolẹ lori ọrọ ibalopọ.

 

Leave a Reply