Faith Adebọla, Eko
Afaimọ ni tiṣa ti wọn porukọ rẹ ni Ọgbẹni Stephen yii ko ni i rẹwọn he lẹnu iṣẹ oojọ rẹ, bi iwadii tawọn ọlọpaa n ṣe ba fidi ẹsun ti wọn fi kan an pe nina to na akẹkọọ ọmọọdun mejila kan, Emmanuel Amidu, lẹgba lo ṣokunfa iku ojiji tọmọ naa ku lẹyin iṣẹju diẹ ti tiṣa na an tan mulẹ.
Nigba ti ALAROYE pe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin, lori aago, lọjọ Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Karun-un, o ni loootọ loun ti gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun, tawọn si ti bẹrẹ iwadii lori ẹ lati mọ bọrọ naa ṣe ṣẹlẹ gan-an.
Ohun ta a gbọ, gẹgẹ biweeroyin Punch ṣe sọ ni pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejila, oṣu yii, niṣẹlẹ naa waye nileewe aladaani Simple Faith Schools, eyi to wa ni Agbara, lẹnu aala ipinlẹ Eko ati Ogun.
Baba ọmọkunrin naa, Ọgbẹni Amidu Akinọla, ṣalaye pe laaarọ ọjọ Tọsidee naa, ọmọ oun ati aburo ẹ obinrin dagbere ileewe foun. O loun fun ọmọkunrin naa ni ẹẹdẹgbẹta Naira (N500), tori iwe kan to ni awọn tiṣa ni kawọn ra, oun si ni ko ko ṣenji to ba ku fun aburo ẹ.
“Ko pẹ lẹyin wakati diẹ ti wọn ti de ileewe ni mo gba ipe lori aago, wọn ni ọmọ mi n bi. Eyi ya mi lẹnu, tori ko si aisan kan to ṣe ọmọ naa ko too kuro nile. Kia ni mo ti de ileewe ọhun, emi ati awọn tiṣa ẹ kan si sare gbe e lọ sọsibitu kan to wa nitosi, wọn si fun un ni itọju pajawiri.
“Lẹyin naa ni mo gbọ pe tiṣa to n kọ wọn lẹkọọ iṣiro lo na gbogbo awọn akẹkọọ rẹ, o ni wọn o ṣe iṣẹ amurele toun yan fun wọn ṣaaju ọjọ naa.
“Mo ranti daadaa pe niṣe lọmọ mi tan tọọṣi mọri lalẹ ọjọ ti wọn yan iṣẹ naa fun wọn, to n ṣiṣẹ amurele ẹ. Ko sidii to fi gbọdọ wa lara awọn ọmọ ti wọn ko ṣiṣẹ wọn.
“Ko pẹ tawọn alaṣẹ ọsibitu naa ni ka gbe ọmọ yii lọ si ọsibitu Fasiti Eko, LUTH, a si ṣe bẹẹ, ṣugbọn bi a ṣe n de’bẹ lọmọ naa dakẹ.
“Bi eyi ṣe ṣẹlẹ lawọn alaṣẹ ileewe naa ti sare lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Morogbo, pe ọkan ninu awọn ọmọleewe awọn ku nigba ti eebi n gbe e. Bawo ni eebi ṣe le mu iku dani ti ki i baa ṣe pe nnkan mi-in wa lẹyin ẹ. Mo fura pe niṣe ni wọn fẹẹ daṣo bo iwa buruku ti tiṣa imọ iṣiro naa hu, wọn o fẹ ki tiṣa naa jiya.”
Bayii ni Baba Emmanuel sọrọ nipa iku ọmọ rẹ, o ni oun fẹ ki idajọ ododo waye lori ọrọ naa.
Ọga agba ileewe naa, Adetayọ Akanji, sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, ati pe loootọ ni tiṣa yii na gbogbo akẹkọọ kilaasi rẹ tori o ni wọn o ṣe iṣẹ toun yan fun wọn. O ni bi tiṣa naa ṣe na wọn, ko ni in lọkan lati ṣe wọn leṣe, o ni iṣẹlẹ yii kan wa bẹẹ ni.