Awọn ọlọpaa le awọn janduku to fẹẹ dana sun ọgba ẹwọn Ikoyi

Faith Adebọla, Eko

Bi ki i baa ṣe pe awọn ọlọpaa ti wọn pe ti wọn tete de si ọgba ẹwọn to wa niluu Ikoyi, nipinlẹ Eko, awọn ọmọ ita to n wọde kiri yii ko sọ pe awọn ko kọ lu ọgba ẹwọn naa, niṣe ni wọn feẹ dana sun un. Awọn ọlọpaa to tete de sibe lo fibọn tu wọn ka. Ṣugbọn pẹlu rẹ naa, eefin ti n ru ni apa kan ọgba ẹwọn yii, gbogbo erongba wọn si ni lati dana sun gbogbo ẹ, ki wọn si tu awọn ẹlẹwọn to wa nibẹ silẹ.

ALAROYE gbọ pe awọn ọmọ ganfe naa ti ya wọ agbegbe ti ọgba ẹwọn yii wa, wọn ti gbe epo bẹntiroolu ti wọn feẹ fi dana sun un lọwọ. Akiyesi yii ni awọn alaṣẹ ọgba ewọn naa ri ti wọn fi sare pe awọn agbofinro.

Ṣugbọn ki awọn ọlopaa too de, eefin ina ti n ru ni ẹgbẹ kan ọgba ẹwọn naa. Oju ẹsẹ ni awọn agbofinro ti da ibọn bolẹ, ti ibọn si n ro lakọlakọ ni gbogbo agbegbe naa titi ti awọn janduku naa fi sa lọ.

ALAROYE pe Alukoro ọlọpaa ipinle Eko, Muyiwa Adejọbi, lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. Ọkunrin naa sọ fun akọroyin wa pe loootọ ni awọn ọmọ ganfe yii ti yi agbegbe naa ka, ṣugbọn wọn ko ti i dana si i.

 

Leave a Reply