Awọn ọlọpaa ti ri mẹtala ninu awọn ẹlẹwọn to sa kuro l’Ọyọọ nipinlẹ Ọṣun

Jọkẹ Amọri

Awọn abule kan nijọba ibilẹ Ejigbo, nipinlẹ Ọṣun, lawọn agbofinro ti mu mẹtala ninu awọn ẹlẹwọn ti wọn sa kuro ni ọgba ẹwọn Aabolongo, niluu Ọyọ, lasiko tawọn janduku kan ya bo ibẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii.

Awọn tọwọ tẹ ọhun ni: Adekanmbi Kọla, Sẹmiu Sali, Nurudeen Garuba, Ismaila Garuba, Nasifi Garuba Quadri Yusuff, Ezekiel Owolabi, Bamidele Kẹhinde, Daodu Emmanuel

Awọn yooku ni, Dele Babatunde, Adeyẹmọ Falọwọ, Ridwan Akinsọla ati Sọla Owolabi.

ALAROYE gbọ pe abule kan niluu Ọla, nijọba Ibilẹ Ejigbo, lawọn kan ninu awọn eeyan naa ti n rin regberegbe kiri. Awọn ara abule naa to ri wọn lo lọọ fi to ọlọpaa leti tawọn yẹn fi waa ko wọn gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣe sọ.

O ni kaakiri awọn abule to wa ni ijọba ibilẹ Ejigbo to paala pẹlu ipinlẹ Ọyọ ni wọn ti ri awọn ẹlẹwọn naa mu.

O fi kun un pe awọn ko ni i pẹẹ ko wọn lọ si ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ, nibi ti wọn yoo ti da wọn pada si ọgba ẹwọn.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ to kọja, lawọn agbebọn kan ya bo ọgba ẹwọn naa, ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn kan silẹ.

Leave a Reply