Awọn olori ti ko kunju oṣuwọn taa ni lo fẹẹ tẹ Naijiria ri – Babangida

Faith Adebọla

Asilo agbara awọn to jẹ olori Naijiria lasiko yii ti fẹẹ tẹ ọkọ orileede naa ri soju agbami. Ibrahim Badamasi Babangida, ajagun-fẹyinti to ṣolori orileede wa lasiko ijọba ologun lo sọrọ yii

yii lọsan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹjọ, oṣu keji yii, lasiko ti Alaga apapọ fun ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Sẹnetọ Iyorchia Ayu, atawọn ọmọ igbimọ alakooso rẹ lọọ ṣabẹwo si i nile rẹ to wa lori oke tente, ilu Minna, nipinlẹ Niger.

Lasiko ti wọn n jiroro, IBB, bawọn kan ṣe maa n pe e, sọ pe:

“Ipo ti Naijiria wa lasiko yii ko daa rara, bi nnkan si ṣe ri fihan pe awọn olori ti ko kunju oṣuwọn, agbara ati aṣẹ to pọ lapọju sọdọ ẹni kan ṣoṣo, iwa imẹlẹ, iwa ẹlẹyamẹya, ati aisi afojusun to dara to, ti fẹẹ tẹ ọkọ Naijiria ri soju agbami.

“Niwọn igba taa ti kuna lati bojuto awọn ipenija to wa ninu eto oṣelu wa ati ẹgbẹ oṣelu pupọ ti wọn n ba ara wọn dije, eyi ti a ti n lo bọ lati asiko ta a ti gba ominira, asiko mi-in lo tun yọju si wa ni ikorita ta a de bayii, ka le fihan pe oṣelu to maa gbe ifẹ ọkan awọn araalu leke, ti yoo si kọyin si iwa imọtara-ẹni-nikan, la fẹẹ ṣe, gẹgẹ bo ṣe wa ni isọri kẹtala ati ikẹrinla iwe ofin orileede Naijiria.”

Bakan naa ni alaga PDP ọhun sọ pe idi pataki tawọn fi ṣabẹwo si Babangida ni lati beere fun atilẹyin rẹ fẹgbẹ oṣelu wọn, ati lati bu diẹ mu ninu omi ọgbọn ati iriri ọkunrin ajagun-fẹyinti naa, tori eekan pataki kan ni Babangida jẹ ninu awọn to pilẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

Ayu ni: “Abẹwo yii ṣe pataki gidi, paapaa lasiko yii ti eto aabo ti mẹhẹ, ipinya ati aigbọra-ẹni-ye n daamu orileede yii lọwọ”.

Ayu rọ Babangida lati ma ṣe kaaarẹ ninu imọran ati iṣapa rẹ fun iṣọkan orileede wa, tori oun naa wa lara awọn eeyan to fẹmi wọn jagun fun iṣọkan wa.

Leave a Reply