Awọn olugbe ilu Ilọrin yari, wọn lawọn o sanwo ina mọ

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Awọn olugbe agbegbe Kankatu, Okelele, Jagun, Alawọnla, Dada ati Ayegbami niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ti tutọ soke, wọn si ti foju gba a, wọn lawọn o sanwo ina fun ileeṣẹ apina IBEDC mọ, latari ina to n daku-daji lojoojumọ.

Gbogbo awọn olugbe agbegbe ti a ti darukọ loke yii ni wọn ti fi ipinnu wọn han fun ileeṣẹ apinna mọnamọna (Ibadan Ditribution Company) IBEDC pe awọn o sanwo ina mọ, tori pe bi eeyan ba fowo ra ooyi, o yẹ ko kọ ni loju ni, ṣugbọọn eyi ko ri bẹẹ lori ọrọ ina ti wọn n mu wa sawọn agbegbe naa.

Wọn ni lẹyin ti ileeṣẹ naa ti kuna lati fun awọn ni ina, awọn naa o ni i san owo ina mọ lati wakati yii lọ. Awọn olugbe agbegbe naa ni ọpọ igba lawọn maa n wa ninu okunkun birimu birimu, sugbọn ṣe ni awọn oṣiṣẹ ajọ naa yoo maa pin biili kaakiri bi oṣu ba ti tẹnu bọpo. Awọn eeyan naa ni wọn o gbọdọ pin biili de agbegbe awọn, bi bẹẹ kọ, awọn yoo fi imu wọn fọn fere.

Ẹni to jẹ alaga ẹgbẹ idagbasoke agbegbe Ayegbami, Malam Issa Salihu, to ba akọroyin wa sọrọ sọ pe ṣe ni gbogbo adugbo maa ṣokunkun batakun, ti wọn o ni i muna wa, sugbọn to ba to akoko ti wọn fẹẹ gbowo ina, wọn le muna wa fun wakati mẹta, ti wọn o si ni i pa a rara.

Alaga ẹgbẹ agbegbe Ibagun /Okelele (IPU) Alhaji Kuranga Morogun, naa fi ẹdun ọkan rẹ han lori bi ileesẹ IBEDC ṣe n sọ wọn sinu okunkun ni tọsan-toru lati igba pipẹ, ti awọn oṣiṣẹ ileesẹ apinna si kọti ikun si gbogbo arọwa ti awọn eniyan agbegbe naa n pa fun wọn. O tẹsiwaju pe awọn ti nawo-nara lori ẹrọ to n peṣe ina lagbegbe naa, ṣugbọn pabo ni gbogbo rẹ ja si. Ohun ti awọn eniyan agbegbe naa kọ si ara ogiri wọn ni “no light, no pay” ko sina, ko sowo.

Nigba ti awọn alaṣẹ IBEDC ẹka ti ilu Ilọrin n sọrọ lori igbeṣẹ ti awọn eniyan agbegbe naa gbe, o ni awọn ti n gbiyanju agbara awọn lati ri i pe ina n tan ni ilu Ilọrin ati agbegbe rẹ ni tọsan toru, sugbọn igbeṣẹ ti awọn agbegbe ti wọn ni awọn ko sanwo ina mọ gbe yii, agbara awọn ko kaa, afi ki awọn kọwe si olu ileesẹ awọn n’Ibadan ko too le niyanju.

Leave a Reply