Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun dana sun akẹkọọ UNIOSUN, nitori ti ko fẹẹ darapọ mọ wọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ṣe ni gbogbo awọn eeyan agbegbe Akede, niluu Oṣogbo, tilẹkun mọri lọsan-an ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn to mẹsan-an niye le ọmọkunrin kan wọ ibẹ.

Ọmọkunrin naa, Ọkẹ Ademiju Victor, la gbọ lẹyin-o-rẹyin pe o jẹ akẹkọọ onipele karun-un ni Fasiti UNIOSUN.

Aago meji ọsan lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa fi ọkada mẹta le Victor debẹ, ṣe ni wọn kọkọ n ṣa a ladaa, nigba ti ada ko wọle ni wọn bẹrẹ si i yin in nibọn.

Nigba to di pe ẹmi ko bọ lara rẹ lawọn eeyan naa binu da bẹntiroolu si i lara, ti wọn si ṣana si i. A gbọ pe wọn duro diẹ ki wọn too kuro nibẹ.

Bi wọn ṣe lọ tan ni awọn kan laduugbo naa sare gbe omi, ti wọn si fi pa ina ara Victor, sibẹ, o ṣi n mi, idi niyẹn ti wọn fi ranṣe pe awọn ọlọpaa ko too di pe wọn gbe e lọ sileewosan kan fun itọju.

Lori iṣẹlẹ naa, Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe loju-ẹsẹ ni awọn ọlọpaa ti lọ sagbegbe ọhun lọjọ naa lati pese aabo.

Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa ati pe awọn ko ti i le sọ boya Victor naa jẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to yatọ si ti awọn ti wọn gbeja ka a mọle naa.

Amọ sa, Alukooro fun Fasiti UNIOSUN, Ademọla Adesọji, ṣalaye fun Alaroye pe akẹkọọ ẹka to n ri si ibi ti wọn ti n kọ nipa imọ oṣelu ni, ati pe awọn akẹkọọ onipari ọsẹ (Part Time Student) ni.

Ademọla sọ pe ohun ti awọn gbọ latẹnu awọn araadugbo ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ ni pe ṣe ni Victor n pariwo pe oun ko fẹẹ ṣe ẹgbẹ wọn lasiko ti wọn n jẹ ẹ niya naa.

 

O waa ke si awọn agbofinro lati tuṣu desalẹ ikoko iwadii naa.

Leave a Reply