Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun fibinu yinbọn pa baale ile mẹta n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Inu ọfọ ni mọlẹbi baale ile mẹta kan, Ọgbẹni Akanbi ti awọn eeyan mọ si Baba Taofeeq, ati awọn ọrẹ meji to ku wa bayii, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn binu yinbọn pa wọn l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lagbegbe Isalẹ-Aluko, ilu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
Iyawo ọkan ninu awọn ti wọn seku pa, Iya Taofeeq, lo ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun ALAROYE. O ni, ‘‘Ko pẹ ti Baba Taofeeq kirun aasamu tan lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, o si lọ sibi ti wọn ti maa n ṣe faaji pẹlu awọn ọrẹ ẹ nita, niṣe ni mo ṣadeede gbọ iro ibọn to dun leralera, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi ẹ, ṣugbọn nigba ti gbogbo nnkan rọlẹ tan ni mo ba jade, mo ba ọkọ mi to n jẹrora iku nilẹ, ẹjẹ ti bo wọn, pẹlu awọn ọrẹ wọn meji ti wọn jọ n ṣe faaji, bi Baba Taofeeq ṣe ku lojiji niyẹn.’’

Olugbe agbegbe naa kan to ba oniroyin sọrọ ṣalaye pe lati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni ija ti n waye laaarin ẹgbẹ okunkun meji, Aye ati ẹgbẹ Ẹyẹ, ti wọn si pa ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ Aye, eyi lo mu ki wọn fẹẹ gbẹsan, ti ọkan lara ọmọ ẹgbẹ Ẹyẹ si maa n lọọ ṣe faaji nibi ti wọn ti pa ọrẹ mẹta yii. Eyi lo mu ki awọn ọmọ ẹgbẹ Aye lọ si agbegbe naa, nigba ti wọn debẹ, wọn ba awọn ọrẹ mẹta ti wọn jokoo, wọn beere ẹni ti wọn n wa. Baba Taofeeq n beere ohun to ṣẹlẹ, to si n gbinyaju lati ba wọn pari ija naa, sadeede ni ọkan ninu wọn binu fabọn yọ, to yin in mọ awọn ọrẹ mẹtẹẹta yii, ti wọn si ku.

Leave a Reply