Adefunkẹ Adebiyi
Iyalẹnu lo jẹ fọpọ eeyan niluu Ibadan, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ PDP kan bẹrẹ si i binu si Gomina Ṣeyi Makinde, ti wọn ni afi ki gomina lọ patapata, awọn ko nifẹẹ rẹ mọ, awọn ko si ni i dibo fun un lọdun 2023 bo ti le wu ko gbiyanju to.
Lati awọn ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ Ọyọ ni awọn ọmọ ẹgbẹ tinu n bi naa ti ṣara wọn jọ, ti awọn agbaagba ẹgbẹ kọọkan naa si wa nikalẹ pẹlu lati fi aidunnu wọn han si Gomina Ṣeyi Makinde.
Niṣe ni wọn ni Makinde depo tan, o gbagbe awọn tawọn ṣiṣẹ fun un lati de ori aleefa ọhun.
Awọn tinu n bi naa ṣalaye pe Makinde ko mu ileri kan bayii ṣẹ fawọn ninu gbogbo eyi to ṣe lasiko to n polongo ibo, lasiko to jẹ awọn lawọn n ṣiṣẹ fun un ko le baa wọle. Wọn ni bo ṣe depo tan lo jẹ pe awọn ti ko tiẹ si nibẹ nigba tawọn n daamu kiri lojo-lẹẹrun, ni Makinde wa n ba ṣe bayii, ti wọn si n jẹ iṣẹ tawọn ṣe.
Bo ṣe ku diẹ ki kọngirẹẹsi PDP waye nipinlẹ Ọyọ, awọn ọmọ ẹgbẹ bii Mulikat Akande Adeọla, Nureni Akanbi, AbdulRasheed Ọlọpọeeyan, Gbọlarumi Hazeem, Fẹmi Babalọla atawọn mi-in ti wọn wa nibi ipade ifẹhonu han yii sọ fawọn ọmọ ẹgbẹ yooku pe awọn ti gba f’Ọlọrun lori bi eyi ṣe ri, ṣugbọn laye awọn, awọn ko ni i fi kadara awọn sọwọ eeyan bii Ṣeyi Makinde yii mọ.
Wọn ni kawọn ọmọ ẹgbẹ ṣa ara wọn lọjọ lasiko idibo kọngirẹẹsi naa, ki wọn ma ja, ṣugbọn ki wọn ka gbogbo ohun to ba ṣẹlẹ nibẹ silẹ, ki wọn fi eyi to ku silẹ fawọn l’Abuja.
Lọrọ kan ṣa, awọn ọmọ PDP tinu n bi yii lawọn ko ba Gomina Makinde ṣe mọ, wọn ni ko ni i de ipo naa ni 2023.