Awọn ọmọ iṣọta kọjú ìjà sira wọn n’Ibadan, wọn yinbọn pa iya to n ta bọọli jẹẹjẹ rẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Iya arugbo to to ẹni àádọ́rin (70) ọdún nibọn ṣeeṣi lọọ ba, to si ṣe kongẹ iku ojiji nigba ti ikọ awọn tọọgi meji fija pẹẹta lagbegbe Idi-Arẹrẹ, nigboro Ibadan, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ.

ALAROYE gbọ pe lóde ariya kan nija ọhún ti bẹrẹ lọjọ Aiku, Sannde, ninu eyi ti wọn ti kọkọ fi ìgò àti àpólà igi han ara wọn léèmọ̀.

Lọjọ keji, ìyẹn Sannde ìjẹta, nija ta a wí yii di eyi ti wọn n fibọn ati oríṣiiríṣii ohun ija oloro jà nigba ti awọn ìkọ to jọ pé ọ́wọ́ dùn ninu ija akọkọ, lọọ tún ẹni wá kúnra wọn, ti awọn ọdọkunrin ti wọn tó àádọta (50) niye ọhun si lọọ ṣigun ba awọn oníjà wọn.

Ninu ija ọhun, eyi to ko ìpayà ba awọn ara àdúgbo bíi Idi-Arẹrẹ, Bẹẹrẹ ati Kúdẹtì, nibọn ti awọn ọmọ igboro naa n yin ranṣẹ sira wọn ti lọọ ṣeeṣi ba iya agba kan ti wọn n pe ni Iya Oluṣọ nibi to ti n yan bọọli lọwọ jẹjẹ ẹ.

Loju ẹsẹ niya onibọọli to ti n lọ bii ẹni aadọrin (70) ọdún naa gbẹmi-in mi.

Yatọ sí iya onibọọli ti wọn yinbọn pa, ọkẹ àìmọye eeyan ti ija yii ko kan rara la gbọ pe wọn fara gbá nínú rogbodiyan naa pẹlu bi wọn ṣe fara pa, ti awọn ọmọ iṣọta wọnyi sí dana sun dukia òmí-ìn ninu wọn.

Nigba to n fìdí iṣẹlẹ yii mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi, sọ pe awọn ọlọpaa ni wọn tete lọọ pana ija ọhun ko tóo di ohun tí yóò bá nnkan jẹ jù bẹẹ lọ.

O ni awọn agbofinro ti gbe oku iya arugbo ti wọn yinbọn pa naa lọ sí ibi tí wọn n ṣe oku lọjọ si nileetura ìjọba ipinlẹ Ọyọ ti wọn n pe ni Adeọyọ Maternity, nigboro Ibadan fun ayẹwo.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa fidi ẹ mulẹ siwaju pe eeyan meji lọwọ ti tẹ ninu awọn to da wahala naa silẹ náà nigba ti iwadii ṣi n tẹsiwaju lori rogbodiyan naa.

 

 

Leave a Reply