Awọn ọmọ ileewe girama lọọ wẹ lodo, lọkan ba ri somi n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọmọ ileewe girama ti Gbagba, n’Ilọrin kan ti wọn o ti i mọ orukọ rẹ lọọ wẹ lodo pẹlu wọn akẹgbẹ rẹ, nibi ti wọn ti n luwẹẹ yii lo ti ri somi, to si mumi yo titi to fi ku lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii.

Ọkunrin kan to pe ara ẹ ni Matiu tọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun akọroyin wa pe oun ri awọn akẹkọọ naa ti wọn to mẹfa ti wọn bẹ lu odo lati wẹ, ṣugbọn nigba ti o ya ni oun ri i ti marun-un ninu wọn n sa lọ, eyi to mu ki oun lọ sibi odo naa.

Mutiu ni awọn sare gbe ọmọdekunrin naa jade ninu odo, sugbọn o ti ku, ti awọn si ri apa ibi ti o ti fori sọ apata lori rẹ.

Titi ti a fi n pari akojọ iroyin yii, wọn ko ti i mọ orukọ ọmọdekunrin ọhun.

Leave a Reply