Wọn ko ti i gba beeli Igboho, wọn tun da a pada satimọle ni Kutọnu

Fun bii wakati mẹwaa ni awon lọọya fi n ba ara won fa a ni ile ejo giga ilu Kutọnu, nibi ti wọn  n gbiyanju lati gba beeli ọkunrin ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Ṣunday Adeyẹmo ti gbogbo eeyan n pe ni Sunday Igboho. Ija naa pọnile-ẹjọ, titi ti awọn adajọ si fi pari ijokoo ọhun ni bii aago mokanla aabọ lọjọ Aje, Mọnde ana yii, wọn ko ri ọrọ beeli naa yanju. Idajọ ti wọn si ṣe ni pe ki Oloye Igboho ṣii wa nitimọle lọdọ awọn lọhun-un nibẹ.

Bẹ ni wọn da Igboho pada si ọgba ẹwọn, bo tilẹ jẹ pe bi igbẹjọ naa ti lọ lẹsẹẹsẹ ko ti han sita faye ri. Lati bii aago mejila lọsan-an ni wọn ti gbe Igboho wọ ile-ẹjọ, nigba ti yoo si fi di bii aago meji lọsan-an, igbẹjọ naa ti bẹrẹ pẹrẹwu. Nitori awọn ero to pọ lapọju, nigba ti wọn gbọ ẹjọ naa debi kan, wọn ni wọn o ni i gbọ ọ ni gbangba mọ, ni wọn ba wọnu ile lọ, wọn o si jẹ ki oniroyin tabi awọn ti ọrọ naa ko kan wọle sibẹ rara: awọn lọọya ati iyawo Igboho, iyẹn Rọpo nikan ni wọn jẹ ko wọle.

Ero pọ debi kan to jẹ awọn ọlọpaa adigboluja ni wọn pe ki wọn waa le awọn ọmọ Naijiria ti wọn jẹ Ololufẹ Igboho, ati awọn ti wọn n ja fun ominira ọmọ Yoruba ti wọn rọ ni ọpọ yanturu lọ si ibi igbẹjọ naa ni Kutọnu. Lẹyin ti awọn ọlọpaa ti de sibẹ, ti wọn si tu wọn ka, awọn eeyan naa tun lọ siwaju kan, nitosi ile-ẹjọ naa, nibẹ ni wọn si parojọ si, ti wọn n reti idajọ. Sugbọn idajọ naa ko de titi aago mejila n lọọ lu loru, ohun ti wọn si gbọ naa ni pe wọn ko ti i gba beeli Igboho, nitori ẹjọ naa yoo ṣi maa tẹ siwaju.

Bayii ni wọn da Sunday Igboho pada si atimọle, ti iyawo rẹ ati awọn lọọya si sin in debẹ, ki wọn too pada si ibusun wọn.

 

Leave a Reply