Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Wọọdu marundinlogoji lo wa ni Rẹmọ, nipinlẹ Ogun, gbogbo wọn pata ni wọn wọde kaakiri Ṣagamu l’Ọjọruu, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Keji yii, ti wọn n kede pe Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo gbọdọ dije dupo aarẹ ni 2023. Aafin Akarigbo ilẹ Rẹmọ ni wọn pari irin naa si, nibi ti wọn ti bẹ kabiyesi lọwẹ pe ko fi lẹta ẹbẹ awọn ranṣẹ si Igbakeji Aarẹ l’Abuja, pe ko waa dije dupo aarẹ gangan.
Awọn ọmọ Rẹmọ labẹ aburada ‘PYO 2023 for President’ yii wọ aṣọ oriṣii kan naa ti wọn kọ akọle yii si, bẹẹ ni wọn de fila rẹ, wọn si rin lati Isalẹ-Ọkọ, ni Ṣagamu, wọn gba Opopona Ewusi, wọn de Sabo, ki wọn too waa pari ẹ saafin Akarigbo, Ọba Babatunde Ajayi.
Nigba to n fi lẹta ti wọn kọ lorukọ gbogbo ọmọ Rẹmọ nilẹ yii ati loke okun fun Akarigbo, Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Rẹmọ tẹlẹ, Ọnarebu John Ọbafẹmi, ṣalaye lori idọbalẹ, pe gbogbo ọmọ Rẹmọ lo ri Ọṣinbajo gẹgẹ bii olori pipe ojulowo ọmọ Rẹmọ to le tukọ orilẹ-ede yii.
O ni ọmọwe nla ni Yẹmi Ọṣinbajo, ọmọ Ikẹnnẹ Rẹmọ, iyẹn lo ṣe pada di Ọjọgbọn, bẹẹ amofin nla tun ni, o ni oloṣelu to moye ni pẹlu, eyi si jẹ awọn amuyẹ to daa fẹni to fẹẹ dupo aarẹ.
Ọnarebu Ọbafẹmi sọ pe, “A waa fun yin ni lẹta yii, ti gbogbo ọmọ Rẹmọ nilẹ yii ati loke okun kọ, ki ẹ ba wa fun Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, pe a fẹ ko sọ erongba rẹ lati dije dupo aarẹ lọdun to n bọ, ko si tete ṣe bẹẹ kia ni. Ẹ jọwọ, ẹ ba wa jẹ ki lẹta yii de Abuja.’’
Nigba to n fesi, Ọba Babatunde Ajayi, ṣeleri pe oun yoo ri i pe lẹta naa de ọdọ Igbakeji Aarẹ l’Abuja. O ṣapejuwe Yẹmi Ọṣinbajo bii olori pipe ọmọ to ṣee mu yangan, ọmọ teeyan fi n tọrọ ọmọ, to jẹ to ba de ipo aarẹ nilẹ yii, awọn yoo maa ranti igba rẹ si rere ni.
Kabiyesi ni ohun to kọkọ ṣe pataki ni pe ki Yoruba di aarẹ ni 2023, iyi ibẹ si ni ko jẹ ọmọ Rẹmọ.
Awọn mi-in ninu awọn oloye ẹgbẹ APC ti wọn tun jade rin irin yii ni Aarẹ Jimi Ọlatunji, Ọtunba Fatai Ṣowẹmimọ, Aṣojuọba Micheal Adesanya, Pasitọ Kọlade Ṣẹgun Ọkẹowo ati bẹẹ bẹẹ lọ.