Awọn ọmọde oloyun mẹrinlelogun kan ree, ile ti wọn ko wọn pamọ si nijọba ti ri wọn

O pẹ ti wọn ti ko wọn pamọ sibẹ ti aṣiri ko tu, afi lọsẹ to kọja yii ti ikọ ọlọpaa Akpakwu, ni Calabar, ipinlẹ Cross River, ṣawari ile naa, to jẹ awọn ọmọde oloyun lo wa nibẹ, ti gbogbo wọn jẹ ọdọmọde, ti wọn ṣenu rogodo-rogodo lọ.

Yatọ sawọn ọmọde oloyun yii, awọn ọmọ wẹẹrẹ mọkanla ti wọn ti bi tẹlẹ ni wọn tun wa nibẹ ti awọn ọlọpaa ri ko ninu ile yii.

Ohun ti wọn n ṣe nibẹ naa ko ju pe awọn kan n mu ọkunrin wa fun awọn obinrin naa lati ba wọn laṣepọ, wọn yoo fun wọn loyun.

Bi wọn ba bimọ tan, wọn yoo gbe awọn ọmọ naa ta fawọn to nilo rẹ, iye ti wọn n ta ọmọkunrin si yatọ si eyi ti wọn n ta ọmọbinrin.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa to ri aṣiri ile yii ko ba awọn to n fi wọn ṣiṣẹ kiṣẹ naa nibẹ, sibẹ, wọn ko awọn oloyun atawọn ọmọde naa kuro nibẹ.

Ajọ to n ri si lilo ọmọde nilokulo ati kiko awọn eeyan lọ sẹyin odi fun iṣẹkiṣẹ (NAPTIP) ni wọn ko wọn fun bayii, bẹẹ ni wọn n wa awọn to ko wọn da sibẹ, ti wọn n ta ọmọ oojọ lai ro ti ọjọ iwaju wọn.

Leave a Reply