Awọn ọmọlẹyin Akeredolu binu sawọn to n gbe iroyin iku rẹ kiri

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ko jọ epe, bẹẹ ni ko jọ aṣẹ, lo n jade lati ẹnu awọn ọmọ ẹyin Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, lori ahesọ kan to gbode pe ọkunrin naa ti ku siluu oyinbo to ti lọọ gba itọju.

Ni nnkan bii ọsẹ mẹta sẹyin lariwo kọkọ gba igboro kan pe ara gomina ọhun ko ya rara, ati pe orilẹ-ede Germany ni wọn gbe e lọ lati lọọ gba itoju

Ni kete ti iroyin yii jade ni Akọwe iroyin gomina, Richard Ọlabọde, ti sare fi atẹjade kan sita lati ta ko o, to si juwe rẹ bii irọ ati ahesọ patapata.
Ọlatunde ni loootọ ni Arakunrin rin irinajo, ṣugbọn ki i ṣe ilẹ Gamani lo lọ, o ni oun atawọn gomina ẹgbẹ rẹ ni wọn jọ kọwọọrin lọ si Dubai fun akanṣe iṣẹ pataki kan ti wọn gbe le wọn lọwọ, koda, o tun fi aworan (fọto) kan lede, eyi to ṣafihan Akeredolu atawọn eeyan kan nibi ti wọn duro si.
Ọlatunde ni ope ati alaimọkan lawọn to n sọ iru ọrọ bẹẹ nitori pe ko sohun to ṣe ọga oun, o ni gaga lara rẹ ya nibi to ti n jaye ori rẹ lọwọ.
Awọn eeyan ko tun fi bẹẹ ri ọrọ yii ro mọ, to si da bii ẹni pe olukuluku tilẹ ti mọkan kuro titi di ibẹrẹ ọsẹ to kọja ti iroyin mi-in tun jade pe gomina ti ku si orilẹ-ede Germany.

Bo tilẹ jẹ pe iroyin abẹlẹ lasan ni wọn fi ọrọ naa ṣe, ti ko sẹni to ni ẹri to daju lati pariwo iru nnkan bẹẹ sita, ṣugbọn ahesọ naa ti fẹẹ maa tan kalẹ ju bo ti yẹ lọ, tawọn eeyan si ti fẹẹ maa gbagbọ pe bẹẹ lo ri, kawọn ọmọ ẹyin Aketi too sare jade lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, lati ta ko iroyin naa.
Akọwe iroyin gomina, Richard Ọlabọde, naa lo tun kọkọ sọrọ sori ikanni ayelujara Fesibuuku rẹ nibi to ti bu ẹnu atẹ lu iwe iroyin ori ẹrọ ayelujara to gbe iroyin ọhun jade.
Ọlabọde ni saka lara ọga oun ya nibi to wa, bo tilẹ jẹ pe ko sọ pato ibi to wa gan-an, to si tun fi fidio kan, nibi ti Gomina Akeredolu ati ẹnikan ti n jo ti ọrọ rẹ lẹyin.
Bi atẹjade ọhun ṣe gori ẹrọ ayelujara tan ni iyawo Gomina, Arabinrin Betty Anyawu Akeredolu, naa sọ tirẹ lori ikanni rẹ, toun naa si n fi bii owe bii owe nu awọn alatako ọkọ rẹ lọrọ lori ahesọ naa.
Lẹyin eyi lọpọ awọn ọmọlẹyin Aketi naa bẹrẹ si i sọ ọkan-o-jọkan kobakungbe ọrọ sawọn ti wọn ro pe wọn wa nidii iroyin iku ọga wọn.

Leave a Reply