Awọn ọmọlẹyin Buhari lawọn naa fẹẹ ṣe iwọde tawọn o

Afaimọ ki awọn ọdọ to n ṣewọde lodi si SARS ati awọn ọmọlẹyin Buhari ti wọn pe ara wọn ni ‘Mo duro ti Buhari’, ‘I stand with Buhari’ ma kọju ija sira wọn pẹlu bi awọn eeyan naa ti wọn ni awọn to miliọnu mẹwaa niye yii ṣe sọ pe awọn naa fẹ ṣe iwọde atilẹyin fun Aarẹ Buhari niluu Abuja ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.

 

Alakooso ẹgbẹ naa, Ogochwku Ezeaku, sọ pe Unity Fountain, Maitama, niluu Abuja, ni iwọde naa yoo ti waye.

O sọ fun akọroyin iweeroyin Punch pe awọn ti kọwe si ileeṣẹ ọlopaa lati beere fun awọn agbofinro ti yoo daabo bo awọn, awọn si gbagbọ pe wọn yoo dahun si ibeere awọn.

Nigba to n dahun ibeere ti wọn bi i lori bi iwọde wọn ati tawọn ọdọ to n fẹhonu han nipa SARS ko fi ni i kọ lu ara wọn, ọkunrin yii ni yatọ si pe oju kan naa ni awọn maa duro si ni tawọn, ti awọn ko ni i lọ kaakiri, o ni awọn olufẹhonu han lori SARS yii ki i ṣe oniwahala, olufẹ alaaafia ni wọn, wọn ko si ni i kọ lu awọn.

O ni awọn pinnu lati ṣe iwọde yii lati fi han Aarẹ Buhari pe ọgọọrọ awọn ọmọ Naijiria ni wọn wa lẹyin rẹ.

3 thoughts on “Awọn ọmọlẹyin Buhari lawọn naa fẹẹ ṣe iwọde tawọn o

Leave a Reply