Faith Adebọla, Eko
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, ti kede pe gbogbo ileewe nipinlẹ Eko, ati aladaani pẹlu ti ijọba ṣi wa ni titi pa, wọn ko ti i le wọle pada lati maa ba ẹkọ wọn lọ.
Kọmiṣanna feto iroyin, Gbenga Ọmọtọṣọ, lo sọ eleyii di mimọ ni Sannde, ọjọ Aiku, ọsẹ yii ninu ikede to ṣe lorukọ gomina.
Ọmọtọṣọ ni gbogbo ileewe nipinlẹ Eko wa ni titi pa titi ti ijọba yoo tun fi kede ọjọ ti wọn maa wọle.