Awọn ọrẹ mẹta ṣe ‘kinni’ fun ọmọbinrin kan ti ha o, adajọ ti ni ki wọn maa ko wọn lọ sọgba ẹwọn

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ile-ẹjọ Majisireeti kan to filu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ṣebujokoo, ti paṣẹ pe ki wọn lọọ ju awọn afurasi ọdaran mẹta kan, Toyin Toheeb, Jamiu Abdullahi ati Aliu Mustapha, sahaamọ ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi waye lori ẹsun ifipa-ba-ni-lo-pọ ti wọn fi kan wọn. Obinrin ẹni ọdun mejidinlogun kan ni wọn fipa ṣe ‘kinni’ fun ninu Atlanta Hostel, niluu Màlété, nijọba ibilẹ Móòrò, nipinlẹ Kwara.

Ileeṣẹ ọlọpaa Kwara, lo wọ awọn afurasi ọhun lọ siwaju ile-ẹjọ lati ṣalaye ara wọn lori ẹsun ifipa-ba-ni-laṣepọ ati igbimọ-pọ lati huwa buruku ti wọn fi kan wọn ọhun.

Agbefọba sọ fun ile-ẹjọ pe niṣe ni awọn afurasi ọdaran yii tan ọmọbinrin yii lọ si yara ọlọdẹ ni Atlanta Hostel, niluu Màlété, lasiko to lọọ pọn omi, ti wọn si n to tọọnu lori ẹ, wọn ba a laṣepọ karakara.

O tẹsiwaju pe ọmọbinrin ti wọn ṣe baṣubaṣu yii lo mu ẹsun lọ sileeṣẹ ọlọpaa pe awọn gende-kunrin naa fipa ba oun laṣepọ lẹyin ti wọn tan oun wọ yara kan ti ọlọdẹ to n sọ ositẹẹli  naa n gbe lasiko ti oun lọọ pọnmi.

Nigba ti ọlọpaa bẹrẹ iwadii lọwọ tẹ awọn afurasi mẹtẹẹta, Toyin Toheeb, Jamiu Abdullahi ati Aliu Mustapha, ti wọn si jẹwọ pe loootọ ni awọn fipa ba ọmọbinrin naa laṣepọ.

Agbefọba naa rọ ile-ẹjọ ko fi awọn afurasi ọhun sahaamọ ọgba ẹwọn titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ibalopọ ti wọn fi kan wọn.

Adajọ Ibrahim Dasuki paṣẹ pe ki wọn lọọ ju wọn sahaamọ ọgba ẹwọn titi igbẹjọ yoo fi waye lori ẹsun ọdaran ti wọn fi kan wọn.

O sun igbẹjọ si ọjọ keje, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.

Leave a Reply