Finidi George di akọni-mọ-ọn-gba tuntun fun Super Eagles

Faith Adebọla

 Ni bayii, ṣinkin bii ẹni jẹ tẹtẹ oriire ni inu gbajumọ agbabọọlu ilẹ wa tẹlẹri nni, Ọgbẹni Finidi George, n dun latari bi wọn ṣe kede rẹ pe oun ni Ifa fọre fun lati bọ sipo akọni-mọ-ọn-gba tuntun fun ikọ agbabọọlu agba ilẹ wa, iyẹn awọn Super Eagles of Nigeria.

Ajọ to n ṣakoso ere bọọlu alafẹsẹgba nilẹ yii, Nigeria Football Federation (NFF) lo buwọ lu iyansipo Finidi, ti wọn si ṣe ikede rẹ bẹẹ lọsan-an ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Ikede yii waye latari ayẹwo ati iwadii ti igbimọ alabẹṣekele NFF to n ri si idagbasoke ere idaraya naa ṣe laipẹ yii lati mọ ẹni ti odu rẹ kun ju laarin awọn ti orukọ wọn wa lakọọlẹ lati bọ sipo naa.

Ẹ oo ranti pe fun bii ọdun kan ataabọ ni Finidi George, ẹni ọdun mejilelaaadọta (52) fi ṣe amugbalẹgbẹẹ fun akọni-mọ-ọn-gba Super Eagles tẹlẹ, Jose Santos Peseiro, to kọwe fipo silẹ loṣu diẹ sẹyin, lẹyin ti wọn fakọyọ ninu idije aṣekagba fun ife-ẹyẹ ẹgbẹ agbabọọlu to peregede ju lọ nilẹ Africa, iyẹn African Cup of Nations, to waye lorileede Cote D’Ivore, nibi ti Nigeria ti ṣepo keji, latigba naa si ni Finidi ti n dele gẹgẹ bii kooṣi Super Eagles, ki wọn too waa buwọ lu iyansipo rẹ bayii.

Nigba ti Finidi fi wa ni ‘ṣango ode’, ọkan pataki lo jẹ ninu ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles, o wa lara awọn ọjafafa lori ọdan to gbafe-ẹyẹ African Cup of Nations wale lọdun 1994, lorileede Tunisia, nibi ti wọn ti fun ikọ naa ni ami-ẹyẹ ẹgbẹ agbabọọlu ti iran wọn dun un wo ju lọ. Bẹẹ lo tun wa lara ikọ Super Eagles to kọkọ kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba ife-ẹyẹ agbaye, FIFA World Cup, lorileede Amẹrika, lọdun kan naa. Ba a ba si ka a leni eji, o to igba mejilelọgọta ti Finidi fi ṣoju Naijiria ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ agbaye. O gba bọọlu agba-buta fun kilọọbu Ajax Armsterdam ati Real Betis, ko too fẹyinti, to si ko buutu rẹ sori pẹpẹ.

Laarin saa perete to fi ṣe adele akọni-mọ-ọn-gba, Finidi ṣaṣeyọri bi Super Eagles ṣe gbo ewuro soju ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Morocco, pẹlu ami ayo meji si ẹyọ kan ninu idije ọlọrẹẹ-sọrẹẹ, bẹẹ lati bii ọdun mejidinlogun sẹyin ni wọn ti ṣe iru ẹ sẹyin, amọ orileede Mali na wọn lẹgba pẹlu ami ayo meji si odo.

Ni bayii to ti bọ sipo kooṣi taara, iṣẹ pataki meji to wa niwaju Finidi George ni bi Super Eagles yoo ṣe ṣaṣeyọri ninu ifẹsẹwọnsẹ ikọ ti yoo lọọ ṣoju orileede rẹ lasiko idije fun ife-ẹyẹ agbaye 2026, wọn yoo ta kan-an-gbọn pẹlu South Africa, niluu Uyo, wọn yoo si tun wa a ko pẹlu Benin Republic, niluu Abidjan, laarin ọsẹ marun-un sasiko yii.

O maa pọn dandan fun Super Eagles lati jawe olubori ninu awọn ifẹsẹwọnsẹ mejeeji yii bi wọn ba fẹẹ rọwọ mu laarin awọn ikọ Iọri C ti wọn wa, eyi ti Naijiria ṣi wa nipo kẹta lori atẹ isọri naa bayii.

Leave a Reply