Dare niyawo oun n yan ale, lo ba gun un pa l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti 

Iyanu nla lo jẹ loju gbogbo eeyan ilu Ado-Ekiti, nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, pẹlu bi baale ile kan ti orukọ rẹ n jẹ Dare Onipẹde, ṣe ṣadeede fa ọbẹ yọ, to si gun iyawo rẹ pa. Ẹsun to fi kan an ni pe obinrin naa n yan ale.

Awọn eeyan ilu naa to ba akọroyin wa sọrọ ṣalaye pe laduugbo Christ Avenue, ni agbegbe Adebayọ, niluu Ado-Ekiti, nipinlẹ Ekiti, niṣẹlẹ naa ti waye.

Wọn ni oloogbe naa ti orukọ rẹ n jẹ Kumapayi Aarinola, ni oun ati baale rẹ ti wa lẹnu wahala naa lati bii ọjọ mẹta pẹlu bi ọkọ rẹ ṣe ni o n ṣe oju meji pẹlu oun pẹlu bo ṣe n yan awọn ọkunrin mi-in lọrẹẹ nita.

ALAROYE gbọ pe tọkọ-taya yii ati ẹnikan ti a ko ti i mọ orukọ rẹ ni wọn ran ọkan ninu eyi to dagba ju lara awọn ọmọ wọn niṣe lakooko ti iṣẹlẹ naa waye. Wọn ni ni kete ti ọmọ naa jade tan ni Onipẹde tilẹkun ile ti wọn n gbepa, to si bẹrẹ wahala lakọtun pẹlu iyawo rẹ lori ọrọ pe o n yan ale to ti n tẹnumọ lati ọjọ yii wa.

Lasiko ariyanjiyan to waye laarin tọkọ-tiyawo naa ni wọn sọ pe baale ile yii gun obinrin to n ṣiṣẹ awọn to n ta oogun yii pa sinu yara wọn, bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ti i le sọ ohun to lo lati gun un pa boya igo tabi ọbẹ ni.

Awọn araadugbo ti wọn gbọ ariwo ni wọn yọju sibi iṣẹlẹ naa lati la tọkọ-tiyawo yii, ṣugbọn ti ilẹkun ti wa ni titi pa. Eyi lo mu ki wọn fi agbara ja ilẹkun ile naa, iyalẹnu lo si jẹ pe niṣe ni wọn ba obinrin yii ninu agbara ẹjẹ to n japoro iku, ti gbogbo ara rẹ si kun fun apa ibi ti ọkunrin yii ti gun un.

Awọn eeyan naa ni wọn sare gbe iyaale ile yii lọ sileewosan, ṣugbọn awọn dokita fidi rẹ mulẹ pe oku obinrin naa ni wọn gbe wa, o ti ku ki wọn too gbe e debe.

Loju-ẹsẹ ni wọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn ọlọpaa leti.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin wa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe awọn ọmọ oloogbe naa lo waa fi iṣẹlẹ naa to agbofinro leti.

 

O ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa.

Leave a Reply