Igbẹjọ gomina Kwara tẹlẹ, Abdulfatai Ahmed, ti wọn fẹsun ikowojẹ kan bẹrẹ n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Igbẹjọ yoo bẹrẹ lori ẹjọ gomina ipinlẹ Kwara tẹlẹ, Abdulfatai Ahmed, ti ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ wa, Economic and Financial Crimes Commision (EFCC), fẹsun kan pe o ko biliọnu mẹwaa Naira jẹ.

Ile-ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, nigbẹjọ naa yoo ti bẹrẹ ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keji yii, ni ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku (EFCC), ẹka tilu Ilọrin, ti ranṣẹ pe Abdulfatai Ahmed, lori ẹsun biliọnu mẹwaa Naira ti wọn ni o poora lasiko iṣẹjọba rẹ laarin ọdun 2011 si ọdun 2019, ti wọn si wọ ọ siwaju ile-ẹjọ.

Ni bayii, ọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii, ni igbẹjọ yoo bẹrẹ.

Leave a Reply