Awọn to n fẹhonu han nitori SARS ba mọto Igbakeji gomina Ogun jẹ

 Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Ọlọrun nikan lo mọ ohun ti yoo gbẹyin ifẹhonu han awọn ti wọn fẹ kijọba fagi le SARS, pẹlu bawọn kan ninu wọn ṣe ba mọto Igbakeji gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ, jẹ, ti wọn tun ṣe ọlọpaa kan leṣe laafin Olowu, l’Abẹokuta, lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii.

Ayẹyẹ ọdun ọmọ Olowu tọdun yii lo n waye lọwọ laafin Olowu, Ọba Adegboyega Dosunmu, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ toun naa jẹ ọmọ Owu wa nibẹ pẹlu awọn alejo pataki, lara wọn si ni Igbakeji gomina, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ.

Inu ile ti wọn ti n ṣọdun naa ni awọn alejo pataki yii wa ti wahala fi ṣẹlẹ nita, awọn kan ti wọn n pariwo pe kijọba fopin si SARS ni wọn gbe iwọde naa de Aafin Olowu, ni wọn ba fẹẹ fagidi wọle, wọn ni Ọbasanjọ lawọn fẹẹ ba sọrọ lori SARS. Ọbasanjọ ba wọn sọrọ alaafia, ṣugbọn ko wọn wọn leti.

Awọn ọlọpaa to wa lẹnu ọna ko fẹẹ ba wọn ja gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ṣugbọn niṣe lawọn afẹhonu han naa bẹrẹ si i ba awọn nnkan jẹ, paapaa ju lọ mọto ti wọn paaki kalẹ, nibẹ ni wọn si ti kọlu mọto Igbakeji gomina yii, ti wọn fọ gilaasi ẹyin rẹ.

Yatọ si eyi, awọn afẹhonu han naa tun fiya jẹ ọkan lara awọn ọlọpaa to wa nibẹ, nigba tawọn ọlọpaa yoo si fi bẹrẹ si i yinbọn soke lati le wọn lọ, wahala naa ti fẹju toto.

Ọwọ pada ba mẹta ninu awọn to fa wahala naa. Ọlọpaa ti wọn ṣe leṣe ti n gba itọju nileewosan.

Ṣe laaarọ kutu ọjọ Abamẹta naa lawọn kan ti kọkọ kora wọn jọ, ti wọn n wọde kiri nipa ọrọ SARS yii, koda, aṣọ oogun bii tawọn ologun ibilẹ ni awọn mi-in wọ ninu wọn. Panṣẹkẹ ni wọn ti bẹrẹ, wọn de Isalẹ-Igbẹhin, Ake atawọn adugbo mi-in l’Abẹokuta, ti wọn n pariwo ‘ENDSARS’ iyẹn ni pe kijọba apapọ pa SARS rẹ

Leave a Reply