Faith Adebọla
Bi iṣẹlẹ jijalẹkun ọgba ẹwọn tawọn ẹlẹwọn si n raaye sa lọ ṣe n ṣẹlẹ lemọlẹmọ lorileede yii, Minisita fun ọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ti sọ pe lọpọ igba, awọn kan lara awọn wọda ti wọn n ṣọ awọn ẹlẹwọn yii lo wa nidii ọrọ ọhun.
Arẹgbẹṣọla ni bi ina ko ba l’awo, ko le jo goke odo, o ni awọn agbofinro ti wọn yan lati mojuto awọn ẹlẹwọn naa ni wọn n gbabọde fun ijọba, iwadii ti wọn ṣe si ti fi han bẹẹ.
Nibi ayẹyẹ ti wọn ṣe lati ki Ọga agba tuntun lẹka amojuto ọgba ẹwọn, Ọgbẹni Haliru Nababa, tijọba ṣẹṣẹ yan sipo, ni minisita ti sọrọ ọhun niluu Abuja, lọjọ Aje, Mọnde yii.
Lara iwa to lodi sofin to lawọn wọda naa n hu ni ki wọn maa ba awọn ẹlẹwọn mu egboogi oloro wọle, ki wọn maa mu awọn kan jade lọọ wẹ nibi tijọba o fọwọ si, tabi ki wọn yọnda fun wọn lati kora jọ laarin ara wọn lai si amojuto.
O ni awọn igbesẹ yii lo n ṣi ọna silẹ fawọn ẹlẹwọn lati raaye jalẹkun sa lọ, eyi si lewu pupọ fun awujọ wa.
O sọ fun ọga agba tuntun naa pe “ẹ gbọdọ wa awọn agbẹyin-bẹbọjẹ wọda to n lọwọ siru iwa aidaa bẹẹ lawaakan, kẹ ẹ si firu wọn jofin. Ko gbọdọ saaye fun awọn alaiṣootọ oṣiṣẹ ọba layiika ọgba ẹwọn.
Yatọ si tawọn wọda to sọ yii, Arẹgbẹṣọla ni ọpọ awọn ẹgbẹkẹgbẹ ti ko bofin mu lo wa kaakiri orileede yii, ti awọn kan lara awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun si ti wa lahaamọ ọgba ẹwọn. Eyi tun maa n mu ki ẹlẹgbẹkẹgbẹ naa wa gbogbo ọna lati jalẹkun ọgba ẹwọn, ki wọn le tu ọmọ ẹgbẹ wọn silẹ.
O ni awọn nnkan ija oloro gidi maa n wa lọwọ awọn ọdaran naa, wọn si maa n bori awọn wọda nigba ti wọn ba gbe wahala wọn de.
Arẹgbẹṣọla ni gbogbo ọna nijọba maa ṣan lati ri i pe iwa a n jalẹkun ẹwọn di nnkan atijọ lorileede yii.