Aye le o, Fẹranmi ati Samuel yin ọlọkada to gbe wọn lọrun sodi ni Mowe

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Ile-ẹjọ Majisireeti kan to n jokoo l’Ọbafẹmi-Owode, nipinlẹ Ogun, ti ju awọn ọkunrin meji kan, Fẹranmi Ajimosun, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, ati Samuel Awotile; ẹni ọdun marundinlogoji sẹwọn.

Wọn ni wọn gbiyanju lati pa ọlọkada to gbe wọn bii ero lagbegbe Ọfada-Mowe, wọn fun un lọrun, wọn si tun ṣa a ladaa lori ki wọn too gbe ọkada Bajaj ẹ lọ.

Agbefọba Adekunle Ọpayẹmi, ṣalaye fun kootu l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, pe lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni awọn olujẹjọ mejeeji huwa yii, ni nnkan bii aago meje alẹ, loju ọna Ọfada-Mowe.

O fi kun un pe ọlọkada kan torukọ ẹ n jẹ Akinọla Adenẹkan ni Fẹranmi pe, pe ko gbe oun lati Oniyanrin, ni Mowe, lọ si adugbo Ọfada-Mowe. O ni bi wọn ṣe n lọ ni Fẹranmi sọ fun ọlọkada naa pe ko duro gbe ọrẹ oun to duro lọọọkan, iyẹn Samuel Awotile, n lọlọkada ba gbe e, wọn si jẹ mẹta lori alupupu naa.

Nigba ti wọn jade soju ọna marosẹ, ojiji ni Fẹranmi fun ọlọkada naa lọrun latẹyin gẹgẹ bi agbefọba ṣe ṣalaye, nibi tiyẹn si ti n gbiyanju lati gba ara ẹ silẹ lo ti bu u lada niwaju ori, bi wọn ṣe wọ ọ bọ silẹ lori ọkada rẹ niyẹn, ti wọn gbe maṣinni naa lọ.

Ọwọ awọn ọlọpaa pada tẹ wọn, nitori Akinọla ọlọkada da ọkan ninu wọn mọ, lọjọ to ri i nibi to ti n ṣiṣẹ lo lọọ sọ fawọn ọlọpaa, bi wọn ṣe mu un niyẹn to si di pe wọn ri ẹni keji naa mu lẹyin igba naa.

Ẹgbẹrun lọna igba ati ogoji (240,000) ni iye owo ọkada naa gẹgẹ bi agbefọba ṣe wi.

Ẹsun igbimọ-pọ ṣiṣẹ ibi, ole jija ati igbiyanju lati paayan ni kootu fi kan wọn, eyi ti ofin ko foju kekere wo eyikeyii ninu wọn, bo tilẹ jẹ pe awọn olujẹjọ lawọn ko jẹbi.

Adajọ Ọmọtayọ Odubanjọ paṣẹ pe ki wọn ko awọn mejeeji da sẹwọn titi digba ti ajọ to n gba kootu nimọran (DPP), yoo fi sọrọ lori ẹjọ wọn.

O sun igbẹjọ si ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹwaa, ọdun 2020.

Leave a Reply