Aye le o, ki lo waa le mu baba ẹni ọgọrin ọdun yii pokunso l’Ekoo

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii lọrọ baba agbalagba kan, Oloogbe Isiaka Ayinde, ẹni ọgọrin ọdun to pokunso sinu ile to n gbe lagbegbe Ararọmi, niluu Imọta, nipinlẹ Eko, ṣi n ya awọn to gbọ lẹnu.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun 2024 yii, ni ọkan lara awọn ọmọ baba onile ibi ti oloogbe ọhun n gbe ri oku baba naa nibi to pokunso so si. Kia lo ti figbe bọnu, ti awọn araale yooku si sare waa wo oku oloogbe ọhun nibi to pokunso si.

ALAROYE gbọ pe ko sẹni to mọ pe oloogbe ọhun, tawọn araale ibi to n gbe maa n pe ni Baba lero buruku kankan lọkan lati gbẹmi ara rẹ nitori pe ko ba ẹnikankan ja, bẹẹ ni ko figba kankan ṣaroye pe nnkan le diẹ foun. Okun ifami ni wọn Ayinde lo to fi pokunso sinu iyara rẹ loru.

Baba onile ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye, Ọgbẹni Mustapha, lo sare ranṣẹ pe awọn ọlọpaa. Nigba ti wọn debi ti oloogbe ọhun pokunso si, wọn ya fọto rẹ, wọn si ni ki wọn sọ oku naa kalẹ lori ikọ to wa. Lẹyin naa ni wọn ke sawọn ẹbi bab yii. Oju-ẹsẹ ni wọn ti palẹ oku rẹ mọ, ti wọn si ti lọ sin in nilana ẹsin Musulumi, wọn ni oloogbe naa ti dagba ju pe ki wọn ṣẹṣẹ maa gbe e pamọ si mọṣuari lọ.

Awọn ọlọpaa ti lawọn maa ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply