Eyi le o, janduku kan lọ ibọn mọ wọda lọwọ, lo ba yin in mọ fọganaisa n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ṣe ni ibẹrubojo gbilẹ lagbegbe Òke-Kúrá, niluu Ilọrin, lọjọ Ẹti, Furaidee ọjọ kẹjọ, osu Kẹta, ọdun 2024 yii, latari bi janduku kan ṣe gun oluṣọ ọgba ẹwọn kan lọbẹ lori, o gba ibọn ọwọ rẹ, o si yin-in mọ araalu to n lọ jẹẹjẹ rẹ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejọ owurọ ni ọkunrin ti ẹnikẹni ko mọ ẹyẹ to su u, bẹrẹ si i gun awọn eeyan to n ba pade lọna lọbẹ, bakan naa lo n ba awọn kẹkẹ Maruwa jẹ.

Ẹni kan tọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye fun akọroyin wa pe, “Bo se de iwaju ọgba ẹwọn Òke-Kúrá, o sọ okuta mọ ọkọ ambulansi ileeṣẹ ọgba ẹwọn naa.

“Ọkan lara awọn oluṣọ ọgba ẹwọn to wa nita lasiko naa gbiyanju lati da a duro, ko dẹkun ijamba ọwọ rẹ, sugbọn ọbẹ lo fi pade oluṣọ naa. O fi ọbẹ gun un lori ati aya, lẹjẹ ba n ṣe ṣuruṣuru.

“Ibi to ti n gbiyanju lati lọ ibọn gba lọwọ wọda naa lo ti yinbọn mọ ẹnikan to n lọ jẹẹjẹ rẹ. Wọn sare gbe ẹni yii ati wọda digbadigba lọ sileewosan ijọba  (General Hospital) fun itọju to peye’’.

ALAROYE gbọ pe wọn mu afurasi janduku yii, wọn si ti fa a le ọlọpaa lọwọ fun iwadii.

Alukoro oluṣọ ọgba ẹwọn Kwara, (Kwara Command Correctional Service), Adegbulugbe Philip Olumide, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun akọroyin wa sọ pe ASP Kabiru, ni orukọ oṣiṣẹ ọgba ẹwọn ti afurasi naa gun lọbẹ, o si ti n gba itọju lọwọ nileewosan bayii.

Ẹwẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Toun, naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun wa, o ni awọn olugbe agbegbe naa ni o ṣee ṣe ko jẹ pe aṣilo oogun oloro lo n da afurasi naa laamu, leyii to mu ki ori rẹ ti maa yi diẹ diẹ.

O ṣalaye pe, afurasi naa ti wa lakata ọlọpaa bayii, awọn si n ṣewadii lọ lori rẹ ati lori iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply