Iṣẹlẹ ijinigbe Kaduna ati Borno, fi han pe Tinubu ko kunju oṣuwọn – Atiku Abubakar

Adewale Adeoye

‘Bi gbogbo nnkan ṣe ri yii, ti eku ko ke bii eku mọ, ti ẹyẹ ko ke bii ẹyẹ, t’ọmọ eeyan paapaa ko f’ọhun bii ọmọ eniyan mọ, ti ọrọ eto aabo ti dori kodo bii ẹyẹ adan, apẹẹrẹ pe olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ko kunju oṣuwọn rara ni.’ Eyi lọrọ to jade lẹnu Alhaji Atiku Abubakar, oludije funpo aarẹ ninu ibo gbogbogboo to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun to kọja lẹgbẹ oṣelu PDP.

Alhaji Atiku Abubakar waa rọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede yii pe ki wọn gbaju mọ ọrọ awọn agbebọn atawọn ọbayejẹ gbogbo ti wọn n fojoojumọ huwa laabi laarin ilu, ki wọn si kapa wọn ni kia.

Atiku ṣapejuwe bi ọrọ eto aabo ilẹ wa ṣe mẹhẹ gẹgẹ bii ohun ti ko bojumu rara, paapaa ju lọ nigba tawọn alaṣẹ ijọba orileede yii ko le yanju wahala naa. Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu bawọn ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n fọwọ yọbọkẹ mu ọrọ ọhun, to fi waa jẹ pe ojoojumọ ni awọn ọbayejẹ yii n ji awọn araalu gbe bo ṣe wu wọn, tijọba ko si ri ohunkohun ṣe si i. O ni apẹẹrẹ pe olori orileede yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, atawọn to n ba a ṣejọba ko le yanju oke iṣoro to n koju awọn ọmọ orileede yii ni ohun to n ṣẹlẹ lọwọ.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii, niroyin tan ka pe awọn agbebọn kan lọọ ji awọn eeyan kan gbe lagbegbe Gamboru, niluu Ngala, nipinlẹ Borno.

Bakan naa ni wọn lọọ ji awọn ọmọleewe alakọọbẹrẹ bii ọọdunrun gbe nileewe wọn l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keje, oṣu yii lagbegbe Kuriga, nipinlẹ Kaduna.

Pẹlu gbogbo iṣẹlẹ ijinigbe ati eto aabo to mẹhẹ lorileede yii lo mu ki Alhaji Atiku Abubakar fi atẹjade kan sita, nibi to ti bu ẹnu atẹ lu ijọba Bọla Tinubu pe wọn ko kun oju oṣuwọn, bẹẹ ni wọn n fọwọ yọbọkẹ mu ọrọ eto aabo ilẹ yii.

Leave a Reply