Eyi ni bi awọn adigunjale ṣe pa ọlọpaa meji lasiko ti wọn fọ banki meji ni Kogi

Adewale Adeoye

Ifa ko fọ rere fawọn agbofinro meji kan pẹlu bi awọn adigunjale ṣe pa wọn sẹnu iṣẹ oojọ wọn lasiko ti wọn ya bo banki ti wọn ti n ṣiṣẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun yii, lagbegbe Anyigba, nipinlẹ Kogi.

ALAROYE gbọ pe First Bank ati Access Bank, to wa lẹgbẹẹ ara wọn lawọn adigunjale ọhun lọọ kọ lu, ti wọn si ji obitibiti owo gbe sa lọ lawọn ileefowopamọ mejeeji ọhun.

Lasiko ti wọn n ṣiṣẹ ibi ọhun lọwọ ni wọn yinbọn pa ọlọpaa meji danu, ti wọn si sa lọ.

Niṣe ni wọn n yinbọn soke gbaugbau lati fi da ipaya sọkan awọn araalu ọhun lasiko ti wọn n ja banki ọhun lole. Bẹẹ lawọn araalu kan fara pa yannayanna lasiko ikọlukọgba ọhun, ti wọn si ti wa nileewosan ti wọn ti n gba itọju lọwọ bayii.

 

 

Leave a Reply